Dokita Oladele

Gbajugbaja onkọwe, agbaṣaga, agbede-larugẹ ni Dokita Ọladele Olusanya. Oniṣegun oyinbo ni, ilu Dallas ni Texas l’Amẹrika to fi ṣebugbe naa lo ti n ṣiṣẹ iṣegun oyinbo rẹ. O ti kọ oriṣii iwe nipa itan Yoruba. Laipẹ yii lo ba Aṣejere sọrọ nipa iṣẹ rẹ ati bo ṣe n ko iṣẹ iṣegun oyinbo pọ mọ imọ aṣa ati iṣe Yoruba. Ohun ti wọn ba SAM AKINROLE sọ lati ilẹ Amẹrika ree.

Aṣejere: Ẹ jẹ ka mọ nipa iṣẹ yin ati ohun to sun oniṣegun oyinbo de idi aṣa ati iṣe?
Dokita Ọladele:
Oriṣii iwe la ti kọ, a kowe nipa itan ati aṣa Yoruba, oriṣii mẹta, a kọ nipa arosọ iṣẹdalẹ Yoruba latọdọ Oduduwa, bẹẹ la tun kọ ni pe bi Ilọrin ṣe ṣubu lasiko Afọnja. A tun ṣe ọkan naa to sọrọ nipa arọso iṣẹdalẹ awọn ọmọ Yoruba lati asiko Oduduwa titi to fi kan iṣubu Ilọrin lasiko Afọnja, ati bi wọn ṣe le awọn eeyan wa kuro lawọn agbegbe ti wọn wa, lasiko iṣubu ijọba Ọyọ lọdun 1836. Iwe keji to sọ nipa awọn iṣẹlẹ to waye ni nnkan bii igba ọdun o le sẹyin, lasiko awọn jagunjagun bii Oluyọle, Ogunmọla, Kurunmi, ati Ogedengbe, awọn nnkan to wa ninu iwe naa niyẹn. Lara awọn nnkan tiwe yii tun sọ nipa rẹ ni bi Eko ṣe di agbegbe ilẹ gẹẹsi lọdun 1861. Bakan naa la tun ṣewe kan nipa itan Herbert Macaulay, Candido Da Rocha, Ọmọwe Abubakara Ọlọrunnimbẹ, to jẹ alakooso akọkọ fun Eko, Ọbafẹmi Awolọwọ, Tai Ṣolarin, Israel Ransome Kuti, atawọn to ṣe laamilaaka ninu iṣẹ amuludun bii Bobby Benson, Roy Chicago, Fẹla ati Susanne Wenger ti gbogbo eeyan mọ si Adunni Oloriṣa. Latigba ti mo ti wa ni kekere ni mo ti nifẹẹ si aṣa, iṣe ati litireṣọ pẹlu awọn nnkan to rọ mọ itan Yoruba. Bakan naa ni Ọlọrun tun fun mi ni ẹbun ati ya aworan pẹlu owo, bẹẹ ni mo tun le kọ daadaa. Iya agba mi lo tubọ jẹ ki n nifẹẹ si awọn itan awọn baba nla wa nilẹ Yoruba, Ẹfunyẹmi lorukọ wọn, wọn jẹ ọmọbinrin gbajumọ ti wọn n pe ni Ṣolesi niluu Ikẹnnẹ, Ẹfunyẹmi tun jẹ ọmọde jagunjagun lasiko ogun Ipẹru, oun lo pada waa di oloye nla ni Rẹmọ.
Aṣejere: Awọn asiko wo le maa n raye ati bojuto iṣẹ iṣegun oyinbo, pẹlu awọn iwe ti ẹ n kọ yii?
Dokita Ọladele:
Oniṣegun oyinbo ni mi, ko fi bẹẹ si akoko fun ẹni to ba n ṣeru iṣẹ bẹẹ paapaa nibi ti mo wa ni agbegbe Dallas niluu Texas nilẹ Amerika. Nitori ifẹ ti mo ni si aṣa ati ede ati iṣe ilẹ Yoruba lo mu ki n maa ṣe gbogbo nnkan ti mo n ṣe yii, akoko ko si fun mi loootọ. Mo tun dupẹ fun iranlọwọ ati ifọwọsowọpọ ti iyawo mi, Kim, n fun mi, oun lo maa n ran mi lọwọ lati ṣe ọpọ awọn iṣẹ ile ati nibi iṣẹ paapaa.
Aṣejere: Lati kekere lẹ ti n kọ ede Yoruba, ki ẹ tilẹ too bẹrẹ ileewe akọbẹrẹ, njẹ awọn ọmọ Yoruba to wa nilẹ okeere n gba awọn ọmọ wọn laye ati sọ ede abinibi, ki lo si fa eyi, ki tun lọna abayọ?
Dokita Ọladele:
Mo lanfaani ati mọ bi a ti n kọ ede Yoruba lati kekere, ki n too wọ ileewe akọbẹrẹ. Ki n too di ọdun mẹsan an, mo ti ka gbogbo iwe D.O. Fagunwa, awọn iwe bii Ogboju Ọdẹ ninu Igbo Irunmọlẹ ati Igbo Olodumare. Mo ti n ka bibeli, ki n too kọ bi a ti n kọ gẹẹsi ni mo ti n kọ ede Yoruba, ṣugbọn gẹgẹ bi ẹyin naa ti sọ, ko ri bẹẹ fawọn ọmọ wa mọ, atawọn to ṣẹṣẹ n dide bayii, paapaa awọn taa bi sẹyin odi. Ohun to si faa ju ni pe awọn obi ko raye fawọn ọmọ wọn mọ, wọn o le kọ wọn lede abinibi wọn mọ, ẹẹkeji ni pe awọn ileewe gan an ko fi bẹẹ faye gba kikọ ede Yoruba, o da bii pe ipinlẹ Eko nikan ni wọn ti faye gba a. Ohun taa le ṣe ni pe kawọn obi tubọ maa ba awọn ọmọ wọn sọ ede naa daadaa ninu ile, ki awọn ileewe wa nilẹ Yoruba ṣe e ni dandan lati maa kọ awọn ọmọ wa lẹkọọ ede Yoruba lati iwe kinni de iwe kẹrin. Ikẹta ni pe; ki awọn eeyan bii temi taa wa niluu oyinbo gbiyanju, ka wa ọna ti a le gba maa kọ awọn eeyan lẹkọọ ede Yoruba, iyẹn awọn ti wọn ko mọ ọn, ti wọn ko si kọ ọ nileewe wọn, ati awọn ti obi wọn ko le kọ awọn ọmọ wọn. Fun apẹẹrẹ, emi atawọn ọrẹ mi kan ti bẹrẹ ajọ aladaani kan niluu Dallas taa pe ni Yoruba Cultural Center Dallas Inc. Lara awọn nnkan taa n ṣe nibẹ nileewe ẹkọ ede Yoruba. A wa lori ẹrọ ayelujara www.yorubacenter.org ibẹ lawọn eeyan ti lanfaani ati forukọsilẹ pẹlu wa lati darapọ mọ wọn nileewe naa.
Aṣejere: Wahala ẹlẹyamẹya to wọpọ niluu oyinbo, ki lẹ le sọ nipa rẹ?
Dokita Ọladele: Ilẹ Amẹrika ni mo n gbe, ibẹ naa ni mo ti n ṣiṣẹ, ẹlẹyamẹya gbilẹ nibẹ gan an, koda wọn kii fẹẹ foju ri awọn eeyan dudu, ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, o ti wa tipẹ lati bii ọdun 1776. Ohun ti mo le sọ ni pe gbogbo wa naa la maa ṣiṣẹ, ka pawọpọ pẹlu awọn ajọ to n wa oriire ati itura awọn eeyan dudu atawọn to ku diẹ kaato fun paapaa ẹgbẹ ti wọn n pe ni Black Lives Matter movement ati NAACP.
Aṣejere: Njẹ a tiẹ le sọ pe a n gbe aṣa ilẹ wa laruge bo ti tọ, ati bo ti yẹ, awọn araalu oyinbo, owo ni wọn maa n fi aṣa wọn pa, njẹ a tiẹ n ronu iru nnkan bẹẹ lọdọ wa?
Dokita Ọladele:
Awa Yoruba naa niṣẹ pupọ lati ṣe ju bi a ṣe n ṣe yii lọ. A nilati maa wọ aṣọ ilẹ wa, paapaa nigba taa ba rinrinajo lọ silẹ okeere. A gbọdọ maa sọ ede wa, paapaa ninu ile, ka si maa ṣeranwọ fawọn to n gbe aṣa ati ede wa bii Yoruba Cultural Center larugẹ lagbegbe wa ati nilẹ okeere. A o le maa reti ijọba ipinlẹ ati apapọ lati maa ṣeyi fun wa. A gbọdọ ri laarin ẹnikọọkan wa atawọn ileeṣẹ adani ti yoo maa da nnkan to ni i ṣe pẹlu aṣa ati ede Yoruba silẹ, ki wọn maa lọwọ sohun to ni i ṣe pẹlu ijo, orin, atawọn ẹgbẹ oṣere tiata silẹ, bii eyi ti Duro Ladipọ atawọn yooku rẹ ṣe ni awọn nnkan bii ọgọta ọdun sẹyin. Awọn nnkan to le ṣafihan aṣa ati ede wa saraye niyẹn o.
Aṣejere: Ẹru n ba awọn agba ilẹ Yoruba pe, o ṣee ṣe ki ede naa ku, ki lawọn nnkan ti ẹ n ṣe lati ma jẹ ko ri bẹẹ?
Dokita Ọladele:
Ohun ti ọkan ninu awọn iwe ti mo kọ da le lori niyẹn. Ka le gbe dide; aṣa ati ede wa, kawọn eeyan le mọ nipa ẹ, ki wọn si nifẹẹ si itan ilẹ wa. Bi awọn onkọtan Yoruba bii temi ba ṣi wa laye, ti wọn n kọ itan Yoruba ati ede oyinbo, ede abinibi wa ko ni i parun lae!