Nitori ati se agbelaruge ati asa ati ise ile Yoruba, ati lati ma le je ki awon ohun itan isembaye yii lo sopin igbagbe, ijoba ipinle Eko ti setan se afihan ere ori itage kan ti akole re je Kurunmi.

Oloogbe Ojogbon Ola Rotimi lo ko itan Kurunmi, bee ni itan naa se afihan ise adari lona oselu ati ti ologun, ati bi a se le lo awon ipo naa fun ayipada awon araalu.
Komisanna fun eto igbafe ati oro asa nipinle naa, Abileko Toke Benson-Awoyinka, lo soro yii nigba to n ba awon oniroyin soro ni Alausa, ni Ikeja, l’Ekoo.
Toke Benson so pe ere ori itage yii yoo tubo fun awon odo lanfaani lati mo nipa ise adari nibikibi ti won ba ti ba ara won.
Gbajumo osere tiata, to dari ere ori itage ohun ti gbogbo eeyan tun mo si Lala gbe oriyin fun ijoba ipinle Eko fun atileyin won lori ere ori itage naa, o ni eyi fihan pe ijoba setan ati se agbende asa wa paapaa laaarin awon odo.
A gbo pe awon eeyan marundinlaaadorun ni won maa kopa ninu ere ori itage naa, bee si ni awon olootu ere naa fee gbe e kaakiri awon ekun idibo meteeta to wa nipinle Eko.

