Remi Martins

Arabinrin Rẹmi Martins ni oludasilẹ ẹgbẹ “Matured Beigns”. Ori ẹrọ ayelujara lawọn ti n ṣẹgbẹ tiwọn, ibẹ naa ni wọn ti maa n bara wọn ṣepade, ti wọn si tun n da ara wọn laraya. Lọjọ ti wọn ṣe ayẹyẹ ọdun kinni wọn ni TOBI ADEYẸMỌ ṣe ifọrọwerọ pẹlu wọn. Ohun ti wọn ba wa sọ nipa ẹgbẹ naa ree.

AṢEJERE: Ẹ jẹ ka mọ yin ju bayii lọ, ati pe ki lorukọ ẹgbẹ yin?

RẸMI MARTINS: Orukọ temi ni Oluwarẹmilẹkun Martins, mo jẹ ọmọ bibi Gbọngan l’Ọṣun. Emi lakọbi laarin awọn ọmọ ti obi mi bi. Emi atawọn ọmọ mi obinrin mẹta la jọ n gbe, emi naa ni mo n gbọ bukata awọn ọmọ naa. Meji ninu wọn ti kẹkọọ jade ileewe giga, ṣugbọn ọkan ṣi wa ni ileewe girama.

AṢEJERE: Ki lorukọ ẹgbẹ yin, ati pe ki lẹ maa n ṣe nibẹ?

RẸMI MARTINS: Orukọ ẹgbẹ naa ni Matured Beings, iyẹn ẹgbẹ awọn to ti balaga. Matured Begins wa fawọn to ti balaga, tabi ti ki i ṣe ọmọde. Ori ẹrọ ayelujara la ti n pade, bii; Facebook ati WhatsApp. Bi a ṣe maa ba ara wa dọrẹẹ la wa fun.

AṢEJERE: Kin ni nnkan tẹẹ maa n ṣe ninu ẹgbẹ yii?

RẸMI MARTINS: A maa n ṣeto idanilẹkọọ, awada, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Bi ọjọ Mọnde; ọjọ iṣẹ wa, ti a maa n jẹ ki awọn olokoowo ṣe ipolowo, bẹẹ ni wọn maa sọ ohun ti wọn n ṣe pẹlu nọmba foonu wọn. Lọjọ Tusde la maa n sọrọ ifẹ laarin awọn ololufẹẹ. Ọjọ Wẹsde lọjọ awọn obi, ti a maa n sọrọ nipa bi awọn obi ṣe le tọju awọn ọmọ wọn. Tọsde la maa n bojuwẹyin, taa maa wo awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin. Ọjọ Fraide la pe ni Freaky Friday wa, ti a maa ṣere ṣawada, sọ nipa ibaṣepọ obinrin sọkunrin. Lọjọ Satide la maa n pade ni adugbo si adugbo. Ọjọ oni taa n ṣayẹyẹ ọdun kan ẹgbẹ wa. A da ẹgbẹ naa silẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹrin, ọdun 2019. O yẹ ka ti ṣe ajọdun yii tipẹ, ṣugbọn tori korona la ṣe sun un sasiko yii.

AṢEJERE: Bawo le ṣe dẹgbẹ naa silẹ?

RẸMI MARTINS: Mo jẹ ọmọ ẹgbẹ “Voice it Out”, eyi to tunmọ si pe sọrọ-soke, eleyii lo fun mi ni imisi ati da tọdọ mi silẹ, to jẹ ẹgbẹ awọn to dagba, nigba yẹn ni ẹgbẹ voice it out, a maa n bara wa ṣere, nigba to ya la da a silẹ lori WhatsApp. Ṣugbọn ẹni to lẹgbẹ yẹn nigba yẹn sọ pe oun ko fẹ ti WhatsApp yẹn. O ni oun maa fagile, mo ni ṣe o le jẹ ki n tẹ siwaju, lemi ati awọn kan fi tẹ siwaju, taa fi da Matured Beings silẹ. Ori ẹrọ ayelujara la ti n ṣe gbogbo nnkan taa n ṣe, paapaa lori facebook ati WhatsApp.

AṢEJERE: Njẹ fun awọn to ti file ọkọ sile tabi fiyawo wọn silẹ nikan ni ẹgbẹ yii wa fun?

RẸMI MARTINS: Rara o, fun gbogbo eeyan ni

AṢEJERE: Bawo le ṣe n yọ awọn kanda kuro ninu irẹsi?

RẸMI MARTINS: Awọn ibeere ati idahun ọmọ ẹgbẹ yẹn lo maa fihan

AṢEJERE: Njẹ ẹ gba awọn ọmọ ẹgbẹ laaaye ati ba ara wọn dọree

RẸMI MARTINS: Anfaani wa fun wọn, wọn kii ṣọmọde, ṣugbọn a maa n sọ fun wọn pe ki wọn kiyesara

AṢEJERE: Kin ni imọran yin fun awọn eeyan?

RẸMI MARTINS: Ki Ọlọrun ran mi lọwọ, o wu mi ki maa ṣe iranlọwọ fun wọn. Mo dẹ fẹ ka ni ẹgbẹ adani to kọja ti facebook, to jẹ pe ti awọn eniyan ba fi ẹkun wọle wọn maa ba ẹrin jade.

AṢEJERE: Kin nimọran yin fawọn ọmọ ẹgbẹ yin lapapọ?

RẸMI MARTINS: Ẹ jẹ ka fifẹ ba ra wa lo, toripe wọn-ni wọn-pe kii jẹ ki ẹgbẹ dagba. Ẹ jẹ ka fẹran ara wa. Ki Ọlọrun ran wa lọwọ.

By Asejere

2 thoughts on “Anfaani pọ ninu ibanidọrẹẹ lori ẹrọ ayelujara – Rẹmi Martins”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp