Zainab Omowunmi

 

 

Ọ̀kan lára àwọn ọmọ àgunbánirọ̀ tí àwọn àjínigbé gbé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjígbé ìpínlẹ̀ Imo ti sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tí ojú rẹ̀ rí ní àkókò tí òun àti àwọn tókù wà nínú àhamọ́ àwọn àjínigbé náà.

‎

‎​Nínú ọ̀rọ̀ ọmọdébìnrin ọun, ó ní àwọn àjínigbé náà máa ń nà àwọn pápa tí àwọn òbí àwọn bá sọ ọ̀rọ̀ tí kò bá wọn lára mu.

‎

‎​Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa irú oúnjẹ tí wọn máa ń jẹ nínú àhamọ́, ó ní gàrí àti omi erẹ̀ ni wọn máa ń fàgídí ní kí àwọn mú.

‎

‎Ti wọn sì máa ń dúnkòókò pe àwọn yóò pa gbogbo àwọn tí àwọn òbí wọn kò bá san owó tí ó yẹ lásìkò.

‎

‎​Nínú àwọn àlàyé tí ọmọbìnrin náà sọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilé̩nuwò tí ó ṣe pẹ̀lú ilé-eṣẹ́ BBC, ó ṣàlàyé pe ìyà gídí ni àwọn jẹ ní àwọn ọjọ́ tí àwọn lò nínú ìgbèkùn náà.

‎

‎​Ó ṣàlàyé síwájú pe wọn máa ń fún àwọn ní ẹ̀rọ ibánisọ̀rọ̀ láti bá àwọn eèyàn àwọn sọ̀rọ̀.

‎

‎Ó ní tí àwọn bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹni tí òbí rẹ̀ bá sọ ohun tí kò yẹ ko sọ, ẹni náà máa ń jẹ ìyà gidi.

‎

‎Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní wọn máa ń fi ìdí ìbọn nàa àwọn, nígbà míràn wọn máa ń gba àwọn ní ẹ̀ṣẹ́ tàbí àbàrà.

‎

‎

‎​Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀, ó ní ago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ọkọ̀ àwọn ti gbera.

‎

‎Ó ní àwọn dúró lọ́nà tí awakọ̀ sí rọ̀ gbogbo èrò inú ọọkọ̀ pe kí àwọn sinmi nítorí ìrìn to wà ní iwájú ṣì jìnna.

‎

‎

‎​Ó ní òun pe àwọn òbí òun láti jẹ́ kí wọn mọ̀ pe alẹ́ ni ọọkọ̀ àwọn yóò fi rìn ìrìn-àjò to kù.

‎

‎Ó ní orun sì gbé òun lọ, ní ìgbà tí òun máa jí ni òun jí sí àhamọ́ àwọn àjínigbé.

‎

‎​Arábìnrin àgunbánirọ̀ náà ní òun kò le sọ ní pàtó bí àwọn ṣe dé inú igbó náà.

‎

‎Ó ní ọ̀rọ̀ náà dà bí sinimá àgbálewo lójú òun nítorí òun kò mọ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀.

‎

‎

‎​Tẹ o bá gbagbé, ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá ọdún yìí ni àwọn àjínigbé gbé àwọn àgunbánirọ̀ ogún àti èrò inú ọkọ̀ kan gbé ní àkókò tí wọn ń rìn ìrìn-àjò láti ìlú Ìbàdàn lọ sí ibùdó àwọn àgunbánirọ̀ tí ó wà ní Abia, tí àwọn kan nínú wọn sí ń lọ sí Akwa Ibom.

‎

‎

‎​Òpópónà Owerri sí Onitsha ni àwọn àjínigbé ti dá ọọ̀kọ̀ wọn lọ́nà tí wọn sì gbé wọn lọ.

‎

‎

‎​Owó ńlá ni wọn ní kí àwọn òbí wọn san láti gbà wọn sílẹ̀ kí àwọn agbófinró orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó rí wọn kó padà wá sílé ní ọjọ́ kẹje oṣù kẹwàá kan náà.

‎

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp