Zainab Omowunmi

 

‎Ileeṣẹ ọlọ́pàá ilu FCT ìyẹn Abuja ti sọ di mimọ pe àwọn ti fi ọwọ́ ofin mu arákùnrin kan Zayyanu Halilu,  to fi agidi ati ipa ba ọmọdébìnrin ọmọdun mejila ni àjọṣepọ to si tun fun ọmọ naa ni oyun.

‎

‎Inu ọkọ̀ kan ni papakọ Airport Bridge Taxi Park nilu Abuja ni Halilu ti ba ọmọbìnrin naa sun.

‎

‎Lẹ́yìn ayẹwo, àwọn ọlọ́pàá ri pe ọmọdébìnrin naa ti ni oyun oṣù mẹta latari ibalopọ naa, eyi to fi han pe Halilu ko ṣẹ ma ba ọmọ naa lo pọ, ọwọ́ palaba rẹ lo segi.

‎

‎

‎Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọ́pàá ilu Abuja SP Josephine Adeh, fi sita ni ọjọ́ Abamẹta Satide yii, o jẹ ko di mimọ pe ẹka ọlọ́pàá to n ri si ọ̀rọ̀ ìjínigbé ni wọn ṣiṣẹ kiri ni ayika papakọ naa ni ọjọ́ kẹji inu oṣù kẹwa ta wa ninu rẹ yii.

‎

‎Ni akoko yii ni wọn ṣe akiyesi pe ìkankan ṣẹlẹ̀ ninu ọkọ̀ Volkswagen aláwọ̀ bulu kan to wa ninu papakọ naa.

‎

‎Ni wọn ba sunmọ lati yẹ inu ọkọ̀ naa wo, ọkọ̀ naa ni gilasi ti eyan ko fi ni ri inu rẹ ìyẹn tinted glasses to si ni nọmba idanimọ KMC567LQ.

‎

‎Àwọn ọlọ́pàá naa salaye pe ọkọ̀ naa n mi titi bi ẹni pe ikan n ṣẹlẹ̀ nínú rẹ ni wọn ba ke si ẹni to wa ninu ọkọ̀ pe ko ṣi ìlẹ̀kùn ọkọ̀ naa, ni gbẹgẹdẹ ba gbin naa.

‎

‎

‎Halilu ni wọn baa pẹlu ṣòkòtò rẹ ni salẹ ti n ko naa si vabu ọmọdébìnrin ti ọjọ ori rẹ kéré gan-an. ‎

‎Lẹ́yìn eyi ni àwọn ọlọ́pàá gbe Halilu ati ọmọdébìnrin naa wa si agọ wọn ni bẹ ni ọmọ naa to sọ di mimọ pe ọmọdun mejila ni oun.

‎‎Iwadi síwájú wa fi han pe ọjọ́ ti pẹ ti Halilu ti ma n fi agidi mu ọmọ naa mọlẹ ninu ọkọ̀. 

‎‎Ọmọdébìnrin yii salaye pe Halilu dun koko mọ oun pe oun yoo pa ti o ba sọ fun ẹnikẹ́ni, oni idi ni yii ti oun ko fi sọ nile. 

‎

Lẹ́yìn ti wọn mu ọmọ naa de ile wòsàn ni àyẹ̀wò fi han pe o ni oyun oṣù mẹta latari gbogbo ipalopọ naa.

‎

‎

‎Ọga ọlọ́pàá ilu Abuja, CP Ahmed Muhammed Sanusi sọ di mimọ pe ọmọdébìnrin naa wa nile ìwòsàn nibi to ti n gba itọju to yẹ nigba ti Halilu si wa ninu ahamọ àwọn.

‎

‎O ni yoo foju ba ile ẹjọ fun idajọ to tọ.

‎

‎Sanusi wa rọ àwọn obi lati ṣe amojuto to yẹ fun àwọn ọmọ wọn pa pa julọ àwọn ọmọdébìnrin.

‎

‎

‎

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp