Zainab Omowunmi

 

‎Àwọn obi àwọn ọmọ agunbanirọ ògùn(20) ti wọn jigbe nipinlẹ Imo ti ke gbanjare sita.

‎

‎Wọn n pariwo ki àwọn ọmọ orile-ede Naijiria gba àwọn kalẹ, wọn ni ki wọn ma jẹ ki àwọn foju sunkún ọmọ.

‎

‎Wọn sọ di mimọ pe owo biliọnu kan naira ni àwọn ajinigbe ni ki awọn lọ wa wa ti wọn si fun àwọn ni gbedeke wákàtí mẹrin lè logun 24hours lati fi wa owó naa ni awa ri.

‎

‎Àwọn obi naa salaye pe wọn ni ti àwọn ko ba ri owo naa laarin akoko ti àwọn fun wọn, àwọn yoo pa ọmọ wọn ti àwọn yoo si fi fọ́nrán wọn ṣọwọ si àwọn obi wọn.

‎

‎

‎Àwọn obi naa salaye síwájú pe owo aadọta miliọnu 50 million naira ni wọn ni ki obi kánkán lọ wa wa lori awọn ọmọ ògùn ti wọn gbe.

‎

‎Àwọn obi naa sọ̀rọ̀ yii di mimọ ni gba ti wọn ke gbanjare igbe ẹgba wa, ẹ ṣanu wa lọ si afin Olubadan Oba Abdul  Rashid Ladoja, ni ile rẹ to wa nilu Bodija ìyẹn ni Ibadan ni ọjọ́ Abamẹta Satide yii.

‎

‎Ni ijoko naa, ọga ọlọ́pàá ipinlẹ Oyo, Olugbenga Abimbola ati ọba Aseyin tilu Iseyin, Oba Sefiu Adeyeri, wa ni kalẹ ti àwọn obi si rawọ ẹ̀bẹ̀ si wọn pe ki wọn ṣe ìrànlọ́wọ́ fun awọn ki awọn ọmọ àwọn le wale.

‎

‎Tẹ o ba gbàgbé Ọjọbọ Tọsde yii ni àwọn ajinigbe ji àwọn agunbanirọ ogun naa gbé nigba ti ọkọ wọn meji n ri ìrìnàjò lati ilu Ibadan lọ si ọgba àgunbánirọ̀ wọn.

‎

‎

‎Ọ́nà Owerri si Onitsha nilu Umunoha nipinlẹ Imo ni àwọn ajinigbe ti da ọkọ̀ méjèèjì lọna ti wọn si gbe àwọn agunbanirọ naa.

‎

‎

‎Ọkàn lara àwọn obi naa to salaye ọ̀rọ̀ sọ di mimọ pe lati ọjọ Ẹti Jimọ ni wọn ti pe àwọn ti wọn si ti bere owo aadọta miliọnu lọ́wọ́ àwọn lati gba àwọn ọmọ naa lẹ ni kánkán.

‎

‎Àwọn obi yii bẹ̀bẹ̀ fún anu ni ọna gbogbo, wọn ni àwọn ko le ri owo naa bẹ àwọn ko fẹ pàdánù ẹ̀mí àwọn ọmọ àwọn.

‎

‎Wọn rọ Ọba Rasheed lati kesi ìjọba fún ìrànlọ́wọ́ to yẹ fun àwọn.

‎

‎Olubadan ati ọga ọlọ́pàá fi àwọn obi ni ọkàn balẹ pe àwọn ko duro rara, o ni àwọn ti n sa ipa àwọn lati ri daaju pe àwọn ọmọ naa wale laipẹ.

‎

‎O fi àwọn obi naa lọ́kàn balẹ pe ayọ̀ ni àwọn ọmọ naa yoo fi dari wale.

‎

‎Ọga ọlọ́pàá Abimbola ni oun n ba àwọn akẹgbe oun to wa nilu Imo ṣíṣẹ pọ lati ri pe àwọn ọmọ naa wale lai ni ifarapa kankan.

‎

‎

‎

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp