Zainab Omowunmi

 

Lẹyin rogbodiyan to ṣẹlẹ̀ ni agbegbe Fowowawo, Ajerogun ati Magbon-Etido ni ijọba ìbílẹ̀ Obafemi-Owode nipinlẹ Ogun laipẹ yii, diẹ ninu awọn olugbe agbegbe naa ti sa kuro ni ile wọn latari ìkọlù naa.

 

 

Ni akoko ti a ṣabẹwo si awọn agbegbe naa ni ọjọ Wẹsde ana ode yii, a ṣe akiyesi pe ọpọlọpọ awọn ile ati awọn ile itaja wa nipo titiipa.

 

Tẹoba gba gbe, ọjọ Aje Monde ọsẹ yii ni wahala ṣẹlẹ̀ ti awọn kan si ka àwọn eyan mọ ori ile, oun ti a gbọ ni pe arakunrin ara Ṣainisi kan ni wọn fẹ jigbe ṣùgbọ́n o ja si asán.

 

Ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Ogun fidi rẹ mulẹ pe eyan mẹfa lo padanu ẹmi wọn nibi ikọlu naa, soja kan, baba ọlọdẹ kan ati awọn eyan mẹrin miran.

 

 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpa, Babaseyi Oluseyi sọ di mimọ pe ọkan lara awọn ajinigbe naa ku ninu ikọlu pẹlu awọn ẹṣọ eleto abo ti wọn lọ fijapẹta pẹlu wọn.

 

Ọpọ eyan lo ti fi agbegbe naa silẹ nitori ibẹru ikọlu miran ti àwọn to ku nibẹ naa si n gbe ninu ojo.

 

 

Ohun ti awọn aralu salaye nipe, ọna to wọ inu Ọfada to jẹ agbegbe ti ileeṣẹ ọlọpa to sunmọ ilu naa julọ wa ko da rara, ti wahala ba wa da, tani awọn yoo ri pe.

 

 

Awọn aralu ni Baalẹ lo pe awọn ọdẹ pe awọn oṣiṣẹ n ja ni ori saiti, nigba ti awọn ọdẹ de bẹ ni wọn ri pe awọn ajinigbe ni, eyi lo fa ti wọn fi yinbọn soke lati kesi awọn akẹgbẹ wọn ki ikọlu naa to bẹrẹ.

 

Wọn salaye pe nigba ti awọn ajinigbe naa ripe awọn eyan jade lati dojú kọ wọn ni wọn bẹrẹ si ni yii ibọn si awọn eyan pẹlu ibẹru pe awọn eyan yoo sa lọ.

 

Bakanaa ni Baale Ajerogun, Nurudeen Salisu salaye pe iru iṣẹlẹ naa ti ṣe ri ni bi ọdun mẹta ṣẹyin ni agbegbe naa to jẹ pe awọn pada san owo ki wọn to fi àwọn ẹni ti wọn mu silẹ.

 

Oni owo miliọnu maarun ni wọn san lati gba a awọn eyan naa kalẹ.

 

 

 

 

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp