
Awọn gomina ilẹ Yoruba ti fẹnu ko pe fifi maaluu jẹ oko lalẹ tabi loru ti di eewọ kaakiri awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba gẹgẹ bi Arakunrin Rotimi Akeredolu ṣe ṣofin ẹ. Nibi ipade ti wọn ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn fulani daran-daran niluu Akurẹ, l’Ondo, ni wọn sọrọ yii lanaa.
Alaga awọn gomina nilẹ wa, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, lo dari ipade naa. O ti wa deewọ ni gbogbo ile Yoruba fun awọn Fulani daran daran lati maa da maaluu lalẹ tabi loru.
Bakan naa ni wọn ṣofin pe awọn Fulani darandaran to ba wa ni ipinlẹ kọọkan gbọdọ forukọ silẹ lọdọ ijọba ipinlẹ ti wọn ba wa.
Yatọ si eyi, wọn tun fofin de awọn Fulani daran daran yii pe wọn ko gbọdọ maa lo awọn ọmọ keekeeke ti wọn ko ti i dagba lati maa da ẹran kiri. O si di eewọ fun ẹnikẹni ninu awọn daran daran yii lati wọ igbo ọba lọna ti ko ba ofin mu.
Ninu ipade naa ni won tun ti fẹnuko pe ko ni i si aaye fun awọn awọn Fulani daran daran lati maa da ẹran kaakiri ibi to ba wu wọn, nitori igbesẹ bẹẹ le da wahala silẹ laarin awọn ati awọn agbẹ.
Lara ohun ti wọn tun fẹnu ko le lori ni mimu eto aabo dan-in-dan-in nipa lilo awọn ọna mi-in fun eto aabo lati ran ijọba lọwọ.
Gomina Kayode Fayẹmi ti ipinle Ekiti sọ pe ko si ẹnikẹni to le awọn daran daran yii, nitori ọpọ wọn lo ti pe nilẹ Yoruba daadaa, awọn to n jẹ kiri inu igbo to n hu iwa ọdaran ni awọn ko fẹ niluu mọ.
