Laipe yii ni Kabiyesi Alayeluwa, Oba Oluwasegun Adeyemi Ajasa, Olaside I, Awise tiluu Onigbongbo ni ijoba ibile Ikeja, l’Ekoo se ayeye odun keji ti won gun ori ite awon baba nla won. Lojo ayeye naa ni kabiyesi gba iko Asejere lalejo ni aafin won, ko too di pe won fi awon oloye kan joye. Won si ba wa soro ranpe nipa odun meji won lori ite. Ohun ti won ba OLUWATOYIN MATHNUEL so ree.

E je ka tun mo oruko yin, kabiesi?

Emi ni Oluwasegun Adeyemi Ajasa, Olaside I, Awise tiluu Onigbongbo

A gbo pe e ti mo tele pe e maa joba, se loooto ni?

Mo ni apeere pe maa joba, sugbon asiko ati akoko ni mi o mo. Eni to so itan fun yin, a jo lo sileewe akobere ati ileewe girama ni, ko si iro ninu e pe lati kekere ni mo ti maa n se bi oba.

Bawo wa le se n sejoba lori ilu Onigbongbo to je awon alakowe lo poju nibe?

Gbogbo ile Awori, ile isese ni, kii se Onigbongbo nikan, Ikeja, Oregun, Alausa, Aguda Ogba, Ikotun, Osodi, alakowe ni wa, sugbon a o fi issese sere rara.

Ki le le so nipa iriri yin laarin odun meji naa?

A dupe f’Olorun niwonba ti Olorun fun wa lagbara, a ko fi sere, a si ri iyipada nla to sele.

Ki lajosepo eyin atijoba, kabiesi?

Ajosepo to dan mroan wa laarin wa pelu ijoba ibile ati ipinle Eko. Ijoba Eko n gbiyanju, won ti se adugbo meta laduugbo wa, Akerele, Ajegunle, Olaside, won si fun wa ni omi ero igbalode.

Bawo le se n ri si eto aabo layika yin, ki le si fe kijoba tun se fun yin?

Eto aabo rorun fun wa ni Onigbongbo. Baraaki ologun ko jinna siwa, ti a ba pe won, owo kan ni won maa n dahun. O je ko ro wa lorun. Laipe lai jinna, a fe ki ijoba ran wa lowo fun ti Town Hall, ati afara elese ni ibuso onigbongbo, ati odo awon ologun yen, nitori awon omo wa ti won n lo sileewe alakoobere, ati mu won koja maa n soro. Bee naa ni ojuna aafin wa nibi.

Ki lawon ipenija yin?

A ni ipenija, sugbon awon araalu femi, won je ki irinajo ro mi lorun, ko seyi ti mo pe ti ki i dide. Won fowosowopo pelu mi, won si je ki irinajo naa ro mi lorun. Mo n be awon omo ilu ki won ma yi iwa won pada ki won maa te siwaju.

Awon odo lo po ju ninu awon ti e fee fi joye, ki lo fa a?

Odo lo le se ilu, diedie lagba n kan ni, awon naa ti n goke agba yen, awon la le sare ri pe, awon to n sise nijoba wa laarin won, awon olopaa wa laarin won.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp