Nojeem Akanbi

Ẹgbẹ́ oselu All Progressives Congress (APC) ní Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe àdúrà àpapọ̀ àwọn ẹ̀sìn ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Tusde fún Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, olùdíje ẹgbẹ́ náà fún ipò gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Dókítà Kadri Obafemi Hamzat, àti àwọn olùdíje mìíràn tí yóò dúró fún ẹgbẹ́ náà nínú ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.

Àdúrà náà wáyé ní pápá ìṣeré Onikan Stadium ní Èkó. Gómìnà Babajide Sanwo-Olu; Dókítà Hamzat; alága APC ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀nàrebu Cornelius Ojelabi; àwọn aṣáájú àti àjọ ẹ̀sìn; àwọn aṣojú ilé ọba; àti àwọn ẹgbẹ́ alátìlẹ́yìn láti inú ìjọba ìbílẹ̀ ogún àti agbegbe idagbasoke mẹ́tàdínlógójì tó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó ló kópa nínú ètò náà.

Àwọn aṣojú Oba Èkó, Oba Rilwan Akiolu; egbe onigbagbo, Christian Association of Nigeria (CAN), tí Reverend Stephen Adegbite ṣáájú; àwọn àjọ Musulumi; àwọn olùsìn ìbílẹ̀; àti àwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ náà náà wà níbi ètò náà.

Sanwo-Olu tẹnumọ́ pé àdúrà ṣe pàtàkì nínú gbogbo ohun tí ènìyàn bá fẹ́ ṣe, ó sì sọ pé, “Kò sí ohun tó tóbi ju àdúrà lọ.”

Ó sọ pé àdúrà náà ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmúrasílẹ̀ ẹgbẹ́ náà fún ìdìbò ọdún 2027. Ó fi kún un pé ẹgbẹ́ náà ti kéde àwọn olùdíje rẹ̀, ó sì ń fi gbogbo ìrìnàjò wọn nínú òṣèlú lé Ọlọ́run lọ́wọ́.

“Ko sí ohun tó tóbi ju àdúrà lọ. Ẹ lè rí i pé èyí jẹ́ àdúrà tí Ọlọ́run ti dáhùn, nítorí gbogbo ohun tí a nílò fún gbogbo ohun tí a bá fẹ́ ṣe ni àdúrà.

“A ti kéde gbogbo àwọn olùdíje wa fún gbogbo ènìyàn. A ti fi gbogbo ìrìnàjò wa àti àwọn olùdíje wa lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Lẹ́yìn èyí, a máa bẹ̀rẹ̀ ìpolongo wa láìsí ìṣòro tàbí ìbẹ̀rù kankan.

“A ti tẹ̀lé ohun tí ẹ̀sìn wa kọ́ wa, lẹ́yìn èyí, a máa jáde lọ ṣe ohun tó yẹ ká ṣe. A kò gba ẹnikẹ́ni tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa sílẹ̀, ìdí nìyẹn tá a fi gbà pé a máa ṣẹ́gun,” ni gómìnà náà sọ.

Hamzat dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àṣeyọrí ètò àdúrà náà, ó sì rọ àwọn tó wà níbi ètò náà láti máa bá a lọ nínú àdúrà fún àṣeyọrí ìdìbò àti fún ìṣẹ́gun Ààrẹ Tinubu àti àwọn olùdíje APC mìíràn.

Ó sọ pé ẹgbẹ́ náà ń fi gbogbo àwọn olùdíje rẹ̀ àti àwọn ìgbòkègbodò òṣèlú rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́.

“Bí a ṣe ń bẹ̀rẹ̀, a gbà pé a gbọ́dọ̀ fi ohun gbogbo lé Ẹlẹ́dàá wa lọ́wọ́. A gbà pé Ọlọ́run ni ó ń ṣàkóso gbogbo ọ̀rọ̀ wa.

“A ń fi Ààrẹ wa àti ìjọba rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́, bákan náà ni a ṣe ń fi gómìnà ìpínlẹ̀ àti ìjọba rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, èmi yóò di gómìnà ìpínlẹ̀ tó kàn, pẹ̀lú gbogbo àwọn olùdíje wa.

“Kí Ọlọ́run gba gbogbo wa là, nítorí ìdí nìyẹn tá a fi wà níbí. A ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run máa bá a lọ ní dídáhùn àdúrà wa, kí ó sì fún wa ní ìṣẹ́gun,” ni Hamzat sọ.

Nínú ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, Alága igbìmọ̀ tó n sètò adúrà apapọ̀ naaa, Alaaji Oyinlomo Danmole, sọ pé awọ́n ṣètò ìpàdé náà láti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ẹgbẹ́ náà sí ìdìbò ọdún 2027 pẹ̀lú àdúrà.

Danmole rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àti àwọn alátìlẹ́yìn APC láti máa gbàdúrà fún àṣeyọrí àwọn olùdíje ẹgbẹ́ náà, pàápàá jùlọ fún ìtẹ̀síwájú ní ìpele orílẹ̀-èdè àti ìpínlẹ̀.

Ó sọ pé, “Èyí ni láti fi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ìdìbò ọdún 2027. Mo rọ gbogbo wa láti máa gbàdúrà fún àwọn olùdíje wa. Ó ṣe pàtàkì láti gbàdúrà fún ìtẹ̀síwájú, nítorí pé ní ọdún mẹ́ta tó kọjá, Ààrẹ Bola Tinubu ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun, nítorí náà, ó yẹ kí a máa gbàdúrà fún un.”

Ó mẹ́nuba ìdásílẹ̀ Nigerian Education Loan Fund (NELFUND), ó sì sọ pé ètò náà ti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àwìn àti ẹ̀bùn owó, tí ó sì ti ràn ju mílíọ̀nù kan lọ́wọ́.

Danmole tún yìn ìjọba Tinubu fún àwọn ètò tó ń ṣe nípa ìdàgbàsókè amáyédẹrùn àti ọ̀rọ̀ ajé. Ó tún yìn ìjọba Sanwo-Olu fún ohun tó pè ní ìyípadà tó ti mú wá sí Ìpínlẹ̀ Èkó àti ọ̀rọ̀ ajé rẹ̀.

Ó fi kún un pé, “Àwọn nǹkan wọ̀nyí náà nílò ìtẹ̀síwájú. Nítorí náà, mo fẹ́ kí gbogbo wa kópa nínú àdúrà fún ìtẹ̀síwájú.”

Bákan náà, Olùdarí Àgbà Ìgbìmọ̀ Ìpolongo PBAT/KOH, Sẹ́nétọ̀ Musiliu Obanikoro, sọ pé ìpàdé náà fún wọn ní àǹfààní láti fi ìrìnàjò ẹgbẹ́ náà nínú òṣèlú lé Ọlọ́run lọ́wọ́ ṣáájú ìdìbò ọdún 2027.

Obanikoro sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò àti ìmúrasílẹ̀ ṣe pàtàkì nínú ìdíje òṣèlú, àdúrà náà ṣe pàtàkì, pàápàá fún àwọn tó gbà pé agbára Ọlọ́run ní ipa lórí ohun gbogbo tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé.

Ó sọ pé, “A kó ara wa jọ níbí lónìí láti fi ìrìnàjò òṣèlú yìí lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Ètò ṣe pàtàkì. Ìmúrasílẹ̀ ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n àdúrà ni ó ṣe pàtàkì jù.”

Ó sọ pé ẹgbẹ́ náà kó ara rẹ̀ jọ láti wá ìtọ́sọ́nà, ààbò àti ọgbọ́n Ọlọ́run bí wọ́n ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìmúrasílẹ̀ fún ìdìbò náà.

Obanikoro sọ pé, “Àdúrà wa rọrùn: kí Ọlọ́run máa ṣáájú wa. Kí ó fún wa ní ọ̀nà tó máa mú ìṣẹ́gun bá ẹgbẹ́ wa.”

Ọ̀gá ìjọba àtijọ́ náà rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC láti gbé àríyànjiyàn inú ẹgbẹ́ sílẹ̀, kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan ṣáájú ìdìbò náà.

Ó sọ pé, “Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ipò ẹnìkálùkù. Gbogbo wa jẹ́ ara ìdílé òṣèlú kan. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àríyànjiyàn inú ẹgbẹ́ fa ìyapa láàárín wa.”

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, APC gbọ́dọ̀ fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan tí ó wà níṣọ̀kan, nítorí àwọn ẹgbẹ́ alatako ń wo ohun tí APC ń ṣe.

Ó fi kún un pé, “A gbọ́dọ̀ fi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, kí a sì wà níṣọ̀kan láti dojú kọ àwọn ẹgbẹ́ alatako fún àǹfààní gbogbo wa.”

Obanikoro tún rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà láti so àdúrà pọ̀ mọ́ iṣẹ́ takuntakun àti ìṣọ̀kan, ó sì sọ pé APC ní àwọn olùdíje tó lágbára ní ìpele orílẹ̀-èdè àti ìpínlẹ̀.

Ó sọ pé, “Ẹ jẹ́ ká gbàdúrà. Ẹ jẹ́ ká ṣiṣẹ́, kí a sì wà níṣọ̀kan láti kọ́ Nàìjíríà àti Ìpínlẹ̀ Èkó tí a fẹ́. Mo lè sọ pẹ̀lú ìgboyà pé, ní ìpele orílẹ̀-èdè àti ìpínlẹ̀, a ní àwọn olùdíje tó dára jù fún ìdìbò náà.”

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp