Zainab Omowunmi

‎

‎Ajọ àwọn ti wọn po ogun oyinbo pọ ni orile-ede Naijiria ìyẹn Nigeria Academy of Pharmacy ti rọ ìjọba apapọ lati sa gbogbo ipa wọn ni ìgbáradì silẹ de arun Ẹbola.

‎

‎Wọn ke si ìjọba apapọ ati gbogbo ẹka eto ilera ni orile-ede Naijiria lati pawọpọ̀ jagun arun Ẹbola ati ajakalẹ àwọn arun burúkú miran.

‎

‎Wọn gbe aba ilana oni koko mẹwa kan kalẹ lati fi koju àwọn àrùn burúkú yii ti yoo si ṣe anfaani fun eto ilera orile-ede Naijiria.

‎

‎Ajọ Nigeria Academy of Pharmacy sọ̀rọ̀ yii di mimọ ninu atẹjade ti wọn fi sita ni Ọjọbọ Tọsde yii.

‎

‎Ẹni to jẹ àárẹ̀ ajọ naa, Ọjọgbọn Lere Baale rọ ìjọba pe ki wọn ṣe agbekalẹ igbimọ ti yoo ma bojuto eto ajakalẹ arun ni gbogbo orile-ede Naijiria ati àgbègbè olú-ìlú àpapọ̀ ìyẹn FCT.

‎

‎Baale ni lotitọ ni orile-ede Naijiria ṣe àwọn àṣeyọrí to pọ lori ati gbogunti arun ẹbola ni ọdún 2014 ni gba to kọkọ bẹrẹ ṣùgbọ́n o rọ won lati ma a gbẹkẹle àwọn àṣeyọrí ti wọn ṣe lori arun naa ni akoko yii, oní kàkà kí wọ́n máa bójú wẹ̀yìn wo àṣeyọrí àtẹ̀yìnwa, oni ìgbáradì to ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ni ki wọn ṣe.

‎

‎O ka àwọn aba ilana oni koko mẹ́wàá wọn sita, ninu rẹ lo ti sọ di mimọ pe yatọ si pe ajọ naa fẹ ki ìjọba àpapọ̀ ṣètò ajọ ti yoo gbogun ti ajakalẹ arun kakiri orile-ede Naijiria, oni ki wọn tun pése ibudo ti wọn yoo ma fi àwọn ti wọn ba fura si pe wọn ni arun naa si gẹgẹ bii wọn ti ṣe ni àtẹ̀yìnwa.

‎

‎Bákannáà, nínú ìlànà ìgbésẹ̀ kókó mẹ́wàá náà, àjọ náà rọ ìjọba láti ṣe àtúnyẹ̀wò kíkún fún ìbaradì àjàkalẹ̀-àrùn ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

‎

‎Ko tan sibẹ, Baale tun rọ ìjọba apapọ lati pèsè àwọn ilé-àyẹ̀wò lábù ati àwọn osìṣẹ́ ti ìṣẹ́ naa ye doju ami ti wọn si ni agbára láti fèsì sí ipe pàjáwìrì

‎

‎​Baale tún fi kún un pé ó pọn dandan láti máa ṣe àyẹ̀wò àkànṣe fún àwọn eyan lati mọ pe àwọn eyan ko sí ninu ewu àjàkalẹ̀-àrùn naa.

‎

‎Baale tun rọ ìjọba lati ṣíṣẹ pọ pẹlu awọn famasi ati ajọ ti n jagun dena arun ìyẹn ajọ Nigeria Centre for Disease Control and Prevention.

‎

‎Wọn sọ̀rọ̀ nipa anfaani nla ti idanilẹkọ ati dena itanka arun Ebola yoo ṣe fun awujọ ti wọn si rọ ìjọba pe ki wọn ṣe atilẹyin to yẹ fun àwọn ti wọn ba ni arun naa.

‎

‎O rọ àwọn eyan lati ṣe àyẹ̀wò ni kete ti wọn ma ri pe ikan ṣe àwọn, oni ki wọn ma ṣe ìtọ́jú ara wọn nile.

‎

‎ Baale ni iṣẹ gbogbo ọmọ orile-ede Naijiria ni lati parapọ̀ gbofun ti àjàkalẹ̀ arun.

Follow by Email
WhatsApp