Zainab Omowunmi

‎

‎

‎Adijedupo ààrẹ orile-ede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ́ òṣèlú African Action Congress,AAC, Omoyele Sowore, tí ṣe ìlérí pé ti oun bá di ààrẹ ni ọdun 2027, òní òun yóò má san owó ìdajì miliọnu gẹgẹ bi owó òṣìṣẹ́ tó kéré jù.

‎

‎Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, Sowore tún ṣe ìlérí pé iná mọ̀nàmọna orile-ede Naijiria kò ní ṣe mọna mọna ni akoko oun gẹgẹ bí ààre.

‎

‎Bakanna ni òun yóò tún ṣe eto ẹ̀kọ́ ọfẹ fún àwọn ẹ̀yán tí òun yóò sì mú ojú tó ọrọ owó ilé tí ń fi ìgbà gbogbo lẹkun yìí.

‎

‎Ọjọ́ Aiku Sọnde yìí ni Sowore ṣe àwọn alaye na ni akoko tó ń sọ àwọn ohun rere tí ẹgbẹ́ òṣèlú AAC ni nilẹ fún ọmọ orile-ede Naijiria.

‎

‎Sowore ni, èrò rere ní ẹgbẹ́ AAC ni fún orile-ede yii, èrò àti lé iṣẹ àti òṣì kúrò nílu ni.

‎

‎Òní ọpọ àwọn olóṣèlú lo ń gbé owó ńláńlá lọ ní ìgbà gbogbo tí ìyà sì ń jẹ aráàlú, nítorí na ni òun yóò ṣe má fún àwọn òṣìṣẹ́ ni owó ìdajì miliọnu gẹ́gẹ́ bí owó tó kéré jù tí ẹni kankan yóò má gba ni owo oṣù.

‎

‎Ó tún sọrọ lórí ìkan ọgbin, Sowore ni òun yóò rí dájú pé àwọn àgbè rí gbogbo ìkan tí wọn nílò ni akoko tó yẹ nítorí iṣẹ agbẹ yóò ṣe iranlọwọ pupọ fún eto ọrọ aje orile-ede.

‎

‎Sowore sọrọ nípa eto abo, òní ìṣàkóso òun yóò rí daaju pé eto abo tó péye wá fún gbogbo eyan tí òun yóò sì gbógun ti ìwà ikowojẹ larin awọn olóṣèlú.

‎

‎Ó sá sọ pé ẹgbẹ́ AAC tí gbaradi lẹkun rẹ rẹ fún idibo ọdún 2027, ó rọ àwọn eyan pé kí wọn má ṣe bẹru, òní kí wọn gba iwe idibo kí wọn sì má múra silẹ.

‎

‎

‎Sowore ni awọn ọmọ orile-ede Naijiria kò nilo alaye lori bi ìjọba tó wà lórí òye kò ṣe ṣe àṣeyọrí, òní ayi padà ní wọn nílò, ẹgbẹ́ AAC ni ìyípadà náà.

‎

‎

‎

‎

‎

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp