Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, lasiko to kọwọrin pẹlu awọn igbimọ ipolongo ibo Aarẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress , lọ ṣabẹwo si aafin Ọba Rilwan Akiolu, Ọba ilu Eko, lati rawọ ẹbẹ si kabiyesi fun atilẹyin rẹ ṣaaju ati lakoko idibo.
Sanwo-Olu, to lewaju awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC lọ si Iga Iduganran, lẹyin to lọ pade awọn agba oloṣelu naa ni papakọ ofuruku ilẹ wa to si kọwọrin pẹlu wọn lọ Iga Ọba Eko, lati lọ gba ire aṣeyọri lẹnu Olowo Eko.
O ṣapejuwe igbimọ ipolongo naa gẹgẹ bi awọ to kaju ilu nitoripe igbimọ naa jẹ akojọpọ awọn eekan oloṣelu bii awọn adari ileegbimọ aṣofin tẹlẹ, awọn Gomina tẹlẹ, awọn abẹnugan atawọn agba ọjẹ ninu oṣelu.
Gomina tun sọ pe, Ipinlẹ Eko duro gẹgẹ bii ibudo ibẹrẹ igbesẹ aṣeyọri bakan naa lo gboriyin fawọn lọbalọba fun akitiyan wọn lori ṣiṣe agbatẹru alaafia, iṣọkan ati eto idagbasoke lapapọ.
Ṣaaju akoko naa ni, Oludari apapọ fun eto ipolongo ibo aarẹ, Sẹnetọ Abdul’aziz Yari, ti sọ pe, abẹwo si aafin kabiyesi wa latiSanwo-Olu, lasiko to kọwọrin pẹlu awọn igbimọ ipolongo Aarẹ juba ati lati bẹbẹ fun atilẹyine Oriade naa ṣaaju idibo gbogboogbo to ma waye lọdun 2027.
Ọba Akiolu ki wọn kaabọ saafin bakan naa ni kabiyesi gbadura fun eto idibo to ma lọ wọọrọwọ laisi oun itajẹsilẹ bẹẹ naa ni oriade naa tun rọ awọn igbimọ ipolongo naa lati duro lori otitọ.

