Ọjọ buruku esu gbe bọn ni ọjọ Aiku ọsẹ yii ni agbegbe ìjọba ibilẹ Yewa South nipinlẹ Ija nla bẹlẹ laarin Kọsitọọ̀mu atawọn onifayawọ, èèyàn kan gbẹmi mi ni gba ti awọọ nla bẹ lẹ laarin awọn kọsitọmu ati awọn oni fayawọ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni ọjọ Aje ọsẹ yii ni pe ija naa bẹlẹ latari pe awọn kọsitọmu fẹ gba irẹsi ti awọn oni fayawọ ngbe wọle si orile-ede Naijiria.

Katowi katofọ, ọrọ naa ti di isu ata yannayanna, ti ohun ibọn si ti bẹrẹ si ni ro.

Ni asiko yii ni ibọn ti awọn kọsitọmu yin ba ọkàn lara awọn oni fayawọ naa ti wọn mọ si Ofe ti o si ku ni oju ẹsẹ.

Inu ọja Ọdan ni ijọba ibilẹ Yewa South ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹ, awọn kọsitọmu si tj gbe oku Ofe lọ.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn ọdọ kan kora wọn jọ ti wọn si lọ dana sun ibujoko awọn kọsitọmu ni agbegbe naa.

Ẹni to jẹ alukoro kọsitọmu ni Ogun Area 1, Chado Zakari ni lotitọ ni ọrọ naa ṣẹ, o salaye pe irẹsi ti wọn fẹ gba lọwọ awọn oni fayawọ naa lo fa ija.

Siwaju si, Zakari ni irẹsi foreign bagi mẹtadinladọta(47) ni wọn gba lọwọ awọn oni fayawọ naa, awọn si ni wọn kọkọ bẹrẹ ija pẹlu awọn kọsitọmu.

Oni yatọ si irẹsi bagi 47 ti wọn gba lọwọ wọn, wọn tun gba ibọn meji ati ọkada mẹrin ti wọn si ti ko gbogbo ẹ lọ fun iwadi.

Zakari ni iwa buruku ni awọn oni fayawọ naa wu lati kọ oju ija si awọn kọsitọmu ti wọn si tun lọ dana sun awọn ibujoko awọn.

Awọn aralu to ba oniroyin wa sọrọ salaye pe ninu iforo ẹmi ni awọn wa.

 

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp