Awọn agbanipa ṣa adije dipo ṣiamanu labẹ asia ẹgbẹ oselu All Progressives Congress APC ni ìjọba ibilẹ Ijede, Oluwatosin Onamade pa.
Ki ṣe pe wọn ṣa Oluwatosin ni kan, wọn tun yin ni bọn, orisirisi oun buruku ni wọn fi ibọn ati ada da lara fun titi ẹmi fi bọ lara rẹ.
Aburo ologbe naa to bawa sọrọ ni ọjọ Aje ọsẹ yii Oluwafemi Onamade, jẹ kodi mimọ pe awọn agbanipa naa ti n tẹle ẹgbọn oun tipẹ ki wọn to ri mu ni ọjọ buruku yii.
Nigba to n salaye iṣẹlẹ naa to ṣẹ ni ọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja yii, Femi ni aṣọ dudu ni awọn agbanipa naa wọ ti wọn si tun bọ oju pẹlu nitori naa ko si ẹni to dawọn mọ bọ tilẹ jẹ pe iwaju ile oologbe ni iṣẹlẹ laabi naa ti ṣẹ.
Oni bi agogo mẹsan alẹ ni awọn agbanipa meji naa de, ti wọn si yin bọn eyi lo jẹ ki amugba lẹgbẹ rẹ salọ.
Femi tun jẹ ka mọ pe iru ikan bayii ti ṣẹlẹ si oun ati ẹgbọn oun ri, ni ọdun 2021 sugbọn Ọlọhun lo dola ẹmi awọn.
Oni ni osu kẹrin ọdun 2021, ni ọjọ Ẹti kan ni ọrọ naa ṣe sugbọn saaju ọjọ naa, awọn ri ẹni sin awọn ni gbẹrẹ ipakọ ti awọn si gba awọn eleto abo, eyin ni ko jẹ ki wọn raye wọle.
Sugbọn wọn ba gbogbo bana to wa ni adugbo jẹ ti ti kan eyi to wa ni ile ẹgbẹ APC to wa ni Ijede ti wọn si tun pa Ifeanyi Godfrey, to jẹ oṣiṣẹ awọn.
Alukoro Ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ naa, CSP Benjamin Hundeyin, fi dawa loju pe iwadi to peye ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa ni ọjọ Aje yii ni akoko ti aba wọn sọrọ.

