Asoju ile Naijiria si orile-ede Philippines tele, Alagba Yemi Farounbi ti so pe pasan ni Aare Muhammadu Buhari je fun awon omo ile yii lasiko yii.
Gege bi Asejere se gbo, baba naa so pe won ti kilo fun awon omo Naijiria tele nipa iru eeyan ti Muhammadu Buhari je, ko too di pe won dibo fun un, ati pe bo se so opo awon oloselu sogba ewon lasiko to wa nile ijoba.
Lori eto redio kan to waye ni Splash FM 105.5FM ti won pe ni Ayekooto ni baba naa ti soro yii.
O ni, “Lodun 2014 nigba ti a n polongo ibo, a so fun awon omo Naijiria pe ki won ma tewogba Buhari, nitori itan re to wa lakosile, paapaa bo ti ti awon oloselu mole nigba naa, ti Baba Obafemi Awolowo naa wa ninu won.
“Alagbara ni Olorun wa, o fi Buhari je wa niya nitori iwa ibi won ni, iya naa la si n je lowo yii.”
Alagba Farounbi tun tako egbe oselu APC fun bi won ti yan elesin kan naa meji fun ipo Aare ati igbakeji re, iyen awon musulumi meji.
