Olori Naomi ati Oonirisa Ogunwusi

Ko tii ju iṣẹju mejidinlaadọta bayii ti Ọọniriṣa, Ọjaja II, Babatunde Ogunwusi funra rẹ ju iroyin naa sori ẹrọ ayelujara. Ohun to sọ ni pe Olori Naomi Ṣilẹkunọla ti bi ọmọkunrin tuntun.
Bo tiẹ jẹ pe Ọọniriṣa ko sọ igba ti Olori bimọ fun wa, ohun taa gbọ ni pe oni yii gan an ni Olori Naomi bimọ ọhun.
Bẹẹ o ba gbagbe, laipẹ yii niroyin ja kaakiri ori ẹrọ ayelujara pe Olori Ọọni ti bimọ, ṣugbọn ti iroyin ọhun pada jẹ irọ, nitori agbẹnusọ kabiyesi ni; ko sohun to jọ bẹẹ rara.
N lo ṣe ba ọpọ eeyan lojiji nigba ti kabiyesi fi iroyin naa sori ẹrọ ayelujara.
Ọpọ awọn to sunmọ Ọọniriṣa ati Olori Naomi ni wọn sọ pe obinrin naa loyun, ko si ni i pẹ ko too bimọ.
Lọrọ kan ṣa, Olori Naomi ti pada bimọ tuntun o!

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp