Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi; Olowo Eko, Oba Rilwanu Akiolu; ati Ooni Ileefe, Babatunde Ogunwusi; nibi ipade awon loba-loba pelu awon asoju Aare ile wa, Muhammadu Buhari nileejoba to wa ni Alausa, Ikeja.

Olowo Eko, Ọba Rilwanu Oṣuọlale Akiolu I, loun ti dariji gbogbo awọn ọdọ ti wọn waa kọlu aafin ọba Eko to wa ni Iga Idunganran ni Isalẹ Eko, o ni; awọn oloṣelu ilẹ wa lo jẹbi.
O sọrọ yii nibi ipade to waye laarin awọn ọba alaye ilẹ Yoruba, awọn gomina ilẹ Yoruba, atawọn ikọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari ran niṣẹ wa silẹ Yoruba ninu eyi ti awọn minisita to jẹ ọmọ ilẹ Oodua naa wa ninu wọn.
Akiolu ni, bi awọn oloṣelu ba ṣohun to yẹ ki wọn ṣe lasiko fun awọn ọdọ to fẹhonu han, ohun to ṣẹlẹ ko ni ṣẹlẹ, o ni, gbogbo ikọlu to ṣẹlẹ lasiko iwọde naa, awọn oloṣelu lo jẹbi, nitori wọn kuna lati ro awọn ọdọ lagbara.
Nigba ti wọn ni ko sọrọ nibi apero naa to waye nileejọba to wa ni Ikẹja, l’Ekoo, Ọba Akiolu tẹnumọ ọn pe oun ti dariji gbogbo awọn ọdọ ti wọn waa kọlu aafin oun, bẹẹ loun si ti gbadura ki awọn alalẹ naa dariji wọn.
Igba akọkọ ree ti Ọba Akiolu maa sọrọ ni gbangba lori bi awọn janduku ọdọ kan ṣe lọọ kọlu aafin rẹ to wa ni Iga Idunganran, l’Ekoo.
Aafin Ọba Akiolu naa wa ninu awọn ibi tawọn janduku kọlu lasiko iwọde awọn ọdọ naa, eyi ti wọn fi gbogun ti awọn ọlọpaa to n ṣeku pa awọn araalu, ti wọn si tun n fiya jẹ wọn lọna aitọ, eyi ti wọn pe ni ENDSARS.
Iwadii Aṣejere fihan pe ọpọ nnkan lawọn janduku naa bajẹ ninu aafin kabiyesi lasiko ikọlu naa. Latigba naa ni kabiyesi ko ti lanfaani ati wi nnkan nipa iṣẹlẹ ọhun, bo tiẹ jẹ pe awọn agbofinro gbe kabiyesi kuro laafin lasiko iṣẹlẹ naa.
Kabiyesi Ọba Akiolu, atawọn ọba ilẹ Yoruba yooku naa wa ninu awọn ọba alaye ti wọn waa ṣepade pẹlu awọn ikọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari ran wa silẹ Yoruba.

By Asejere

2 thoughts on “Mo ti dariji awọn to kọlu aafin mi, awọn oloṣelu lo jẹbi – Ọba Akiolu”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp