Dunni Olanrewaju

Laide Gold

Gbajumo olorin ẹmi, Lady Evangelist Dr.  Dunnni Ọlanrewaju tawọn eeyan mọ si   Ọpẹlọpẹ Anointing lo ṣalaye irinkerindo igbesi aye rẹ laipẹ yii nigba to n ṣe ayẹyẹ ọjọọbi ọgọta ọdun lori ilẹ alaaye.

Ninu ayọ nla pẹlu ifẹmi imoore han si Ọlọrun lo ti ṣalaye pe, irin ajo oun nile aye yii paapaa julọ lati le jẹ alẹnulọrọ lawujọ kun fun ohun oriṣiiriṣii toun si n fogo fun Ọlọrun bi ọrọ naa ṣe jasọpẹ nigbẹyin.

“Gbogbo ọna ni satani fi gbogun ti mi ṣugbọn lọjọ manigbagbe kan ni Ọlọrun gbe mi bori ti mo wa n yọ ayọ nla lonii’

Obinrin Ajihinrere naa sọ pe bi oun ba ro arojinlẹ lori igbesi aye oun, awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin atawọn idojuko leyi to gbe oun de ebute aṣeyọri, ṣe lọrọ ohun maa n mu oun ranti owe Yoruba to sọ pe, ironu pupọ ni i fa ẹkun asunndakẹ tori naa ṣe loun n fogo f’Ọlọrun lori ore ọọfẹ alailabawọn toun ri gba.

Lara koko nnkan to mu ki obinrin naa maa dupẹ aduudutan naa leyi to sọ pe, ṣeni oun ko ba maa gba aaru l’Ọja Mile 12 l’Ekoo tawọn eeyan ko ba maa pe oun ni alabaru ṣugbọn aanu ati oju rere toun ri gba lọdọ Ọlọrun loun fi di eeyan pataki lawujọ ti wọn n pe ni gbajugbaja olorin ẹmi nipa ifami ororo yan nitori naa iyin Ọlọrun ko ni i tan lẹnu oun titi lae.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp