Laide Gold

Ṣeni ifẹ n pa ọga awọn onimọto l’Ekoo; Alaaji Musiliu Akinsanya ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluọmọ bi ọti bayii, ko deede ṣe ale gẹgẹ bi ẹni ti ko ri obinrin ri, koda o ti fẹ awọn arẹwa obinrin sẹyin ṣugbọn ṣeni ifẹ ọmọ Edo to ṣẹṣẹ n fẹ naa n paa bi ọti.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ Aṣejere lọwọ, ilu Turkey lawọn mejeeji wa bayii ti wọn n gbafẹ bẹẹ titi di asiko yii, iyalẹnu lo ṣi n jẹ fawọn ọrẹ ọmọbinrin arẹwa naa torukẹ ẹ n jẹ Ehizogie Ogbebor pe o le fẹ MC Oluọmọ bo ṣe kawe to, iṣẹ kọndọkitọ to jẹ ibi pẹlẹbẹ iṣẹ mọto ni MC Oluọmọ ti bẹrẹ koda ko le sọ ede geesi ko ja geere lẹnu bẹẹ ọmọbinrin arẹwa naa n kanju lati yi orukọ rẹ pada si abilekọ Ehizogie Akinsanya.

Loootọ, Ehi naa kii ṣe wundia toripe agbebọ adiyẹ ni, yatọ si pe o rẹwa, oun naa ti tọ ile ọkọ meji wo, bẹẹ lo ti bimọ mẹta ṣugbọn ina ko wọ mọ laarin oun atawọn ọkọ to bimọ fun.

Laipẹ yii ni wọn ni ọmọbinrin naa tọjọ ori ẹ ko ju ọdun marunlelọgbọn lọ, to tun jẹ oludari ileeṣẹ Sayaveth Decor & Hotel kọ ile kan ara ọtọ onipalọ meje funra ẹ leyi to fihan pe oun paapaa ni ṣenji lapo ati pe olowo tabua lọkọ rẹ; Ọgbẹni Kenneth Bramor to ṣẹṣẹ kọ silẹ nitori naa, o ṣoro lati sọ pe tori owo lo ṣe fẹẹ MC Oluọmọ.

Ninu ọrọ tawọn ti wọn sunmọ MC daadaa sọ ni wọn ti ṣalaye pe, bi igbin fa lawọn ololufẹ mejeeji n ṣe koda wọn kii fẹẹ fi ara wọn silẹ fun iṣẹju kan.

Bawo lawọn mejeeji ṣe wa pade ni wọn ti tẹ siwaju ninu alaye wọn pe, lọdun 2019 ni Musiliu Akinsanya kọ ile fawọn iyawo ẹ mẹtẹẹta lasiko naa ni Ehi wa polowo iṣẹ rẹ pe oun le ṣe awọn ọṣọ to dara sinu awọn ile naa, lẹyin to gba iṣẹ naa tan, ko jẹ ko tan sibẹ ṣe lo tun gba ọkan MC naa mọ latigba yẹn ni ina ifẹ ti n jo laarin wọn ti wọn si de fila mawobẹ si nnkan tawọn eeyan n sọ.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp