* O ni oun ni Olori ẹbi oloogbe naa

Laide Gold

Gbajumọ oṣere fuji Alaaji Wasiu Ayinde Marshall, ti jẹ ko di mimọ fun gbogbo eeyan pe, Ija ti pari laarin oun atawọn ẹbi oloogbe Dokita Sikiru Ayinde Barrister lẹyin ọdun kẹwaa gbako ti oludasilẹ orin fuji naa ti silewo.

Bẹẹ o ba gbagbe, ọdun 2010 ni Barrister tawọn eeyan tun mọ si ‘Mr Fuji’ dagbere faye leyi to pe ogun ọdun bayii, ṣugbọn ni kete ti wọn ṣe ayẹyẹ ikẹyin fun ọga fuji naa tan ni Ija nla ti bẹ silẹ laarin awọn mọlẹbi Alhaji Agba ati Wasiu Ayinde K1 ti ija naa tun ran mọ awọn oṣere fuji miiran.

K1 gbe e sori ikanni Ayelujara Facebook ẹ lọjọ kinni oṣu yii pe, ija to wa laarin oun ati awọn ẹbi Barrister ti pari bẹẹ lo ti di afisẹyin ti eegun n fi aṣọ.

Ohun ti K1 kọ sori nnkan to gbe jade naa ni pe oun ti pari ija to wa laarin oun atawọn mọlẹbi Ọga oun ninu ipade kan pẹlu ọga olorin ti oloogbe naa maa n tiju fun iyẹn Chief Commander Ebenezer Obey Fabiyi, ipade ipẹtusija naa waye ninu ile rẹ niluu Ikẹja l’Ekoo. Awọn ọmọ atawọn iyawo Barrister ni wọn peju pesẹ sibi ipade naa nibi ti wọn ti kede kogun-o-min.

Ẹni to ṣe atọkun ipade naa ni ọrẹ timọtimọ Wasiu Ayinde,  Alhaji Adisa Osiefa, oun naa lo ṣe alarina bi alaafia ṣe pada sinu ẹbi naa.

Ni bayii, K1 ti kede gẹgẹ bi olori ẹbi idile Barrister lati sami ayẹyẹ ọdun kẹwaa ti Ọga olorin naa ti doloogbe lọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun yii, o rọ gbogbo awọn ti wọn maa n gbe iroyin pooyi ẹnu kiri pe, ki wọn wa nnkan mi in ṣe toripe ẹbi awọn ti to.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp