
Adajọ Ọlabisi Akinlade tileẹjọ giga ilu Eko ti kọ lati fun gbajumọ Pasitọ nni, Ọladele Ogundipẹ, tọpọ eeyan mọ si Genesis, tii ṣe olori ijọ Cele to wa ni Alagbado, l’Ekoo.
Lọọya Genesis, Ọgbẹni Ọlanrewaju Ajanaku lo gbe aba ọhun wa siwaju adajọ pe ara ọkunrin naa ko ya, nitori o ni ẹjẹ riru ti wọn n pe ni hapatẹnṣọn, ati ọgbẹ inu ti wọn n pe ni ulcer. Ṣugbọn ṣe ni adajọ naa kọ eti ikun sọrọ ti lọọya naa sọ.
Bakan naa ni agbẹjọro Genesis tun sọ fun adajọ pe ojiṣẹ Ọlọrun to n ṣẹwọn lọwọ naa ni aisan itọ ṣuga, nitori naa ko le rọrun fun un lati gba itọju lẹwọn.
Ṣugbọn gbogbo ọrọ ti agbẹjọro sọ yii ni Arabinrin Rotimi Odutọla tako. Odutọla ni agbẹjọro ijọba lori ọrọ naa.
Bẹẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni wọn sọ Genesis sẹwọn ọdun meji nitori pe o ṣe gbaju ẹ fun obinrin kan lowo tiye rẹ to miliọnu mẹrinla naira.
