Ojuoluwakotimi Olusina

Wolii Ọlagoroye Faleyimu ni oludasilẹ ijọ Mountain of Miracles & Blessings, to wa niluu Badagry, l’Ekoo. Ọpọ asọtẹlẹ ni ojiṣẹ–Ọlọrun yii ti sọ, paapaa awọn to ti wa si imuṣẹ.

O pẹ ti wọn ti maa n ba Aṣejere sọrọ nipa awọn nnkan ti Ọlọrun ti fi han wọn pe yoo ṣẹlẹ; lagbo oṣelu, ninu iṣejọba, lẹka ọrọ aje, ati laarin awọn ọba alade ilẹ Yoruba.

Ni bii ọdun meloo kan sẹyin ni Alagba naa sọ asọtẹlẹ nipa Funkẹ Akindele, lara ohun ti wọn si sọ nigba naa ni pe Funkẹ ko ni le lade lori bii ọkọ, bẹẹ ni wọn si tun sọ pe ọmọbinrin naa ko ni bimọ laye, nitori Ọlọrun ko yan awọn nnkan meji yii fun un. Okiki, ọla ati ọrọ nikan ni Ọlọrun yọnda fun un.

Nigba ti Alagba naa n ba Aṣejere sọrọ lopin ọsẹ yii, Wolii Faleyimu ni, oun maa sọ fun gbogbo ọmọ Naijiria ohun ti Ọlọrun sọ nipa Funkẹ Akindele ati eto oṣelu ilẹ wa. O loun maa ju ọrọ naa sita ki oṣu yii too pari.

Laipe yii, won tun ti ba Asejere soro nipa eto idibo to n bo lona. Ohun ti won ba wa so ree.

A fee so nipa oro orile-ede wa, mo ti so tele pe to ba di osu keje, a maa so nipa ohun to maa sele nile wa. Nipa awuyewuye ibo ti won fee di nile wa, ati bi won se fee du ipi aare la fee so.

Ko si egbe kan to maa se Aare ninu awon egbe to n pariwo kiri lowo lonii. Ati Bola Tinuu, Atiku Abubakar, Peter Obi, ko seyi to maa di Aare ninu gbogbo awon oloselu ti mo daruko yii.

Ohun ti Oluwa fi han mi ni pe ko seyi to maa di Aare ninu won, egbe tuntun lo maa dide. Isele nla kan maa sele to je pe egbe tuntun ti won ba da sile lo maa fa Aare tuntun jade.

Bee la ti so tele pe Aare Muhammadu Buhari, Olorun ni ko wa gbadun emi e ni, ko si nnkan to maa se e, o maa lo odun mejo e tan, ko seni to maa yo o nipo rara, nitori Olorun ni ko wa gbadun emi e ni. Titi to fi maa lo, bijoba re se maa ri niyen, ti ara maa ni awon eeyan. Sugbon mo fe kawon araalu mo pe ko ri Aare lori Tinubu ati Atiku.

Yoruba lo maa gbajoba lowo Buhari, Kristeni si lonitohun maa je, sugbon gege bi a ti fi han mi, mo fi n da awon eeyan loju pe ko si Aare ninu Tinubu ati Atiku, ki won sare ju bee lo. Ko seni ti Olorun yan ninu won.

Odun 2025 ni ile yii maa bere si i ni isinmi, a ti n so o tele, o di odun 2025 ni orile-ede maa bere si i ni alaafia. Eni to ba wole, orile-ede yii maa koko mi fun odun meji, ko too di pe nnkan maa derun. Ipinle Ondo ni eni to maa gbajoba ti n bo. Nigba ti asiko ba to, o maa dide. Ojo ola Naijiria maa da, eni ti Oloun si fee mu ko ni ju ogota odun si odun marundinlaadorin lo, kii se awon agbalagba. Ilu yii si maa da a, tawon orile-ede nla nla maa ma wa lati beri fun wa.

Bakan naa ni iji maa bere si i gbe awon oba lo, bee ni o maa ri fun awon onitiata naa, ki won maa gbadura ki won ma padanu ninu won.

A tun gbodo gbadura fun ijamba ina lori awon ileese nla nla ile wa ati oja, pe ki won ma ba a gbina, nitori o maa sakoba fun eto oro aje wa gidi.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ati Obafemi Hamzat lo maa sejoba ipinle Eko gbeyin nitori ijoba mi in maa wole, ti kii se APC abi PDP. Egbe tuntun lo maa wole.

Tinubu da bii Adonija, ninu bibeli, kii se Solomoni, oun lo loun fee je Aare, sugbon Olorun ko lowo si i. Dugbedugbe maa jabo, mimi maa mi, sugbon awon ologun ko ni gbajoba, kiki awon to ba sunmo Olorun nikan lo maa rije rimu.

Nipa ti ibo Osun, ohun ti Oluwa fi han mi ni pe Adeleke wole sugbon seni won gbe e seyin ilekun, ohun to si sele si Aare ile wa naa niyen.

Bi Tinubu ba gbe owo wa sibi mi o ni gba a lowo e, nitori ohun ti Olorun so niyen. Bi ko ba si jawo, o see se ko gba emi e lo. Bi a se kilo fun MKO Abiola lojosi naa niyen.

Nipa orile-ede Oodua, ko si nnkan to n je bee, Naijiria ko le pin, o maa mi ni. Olorun ko fi iyapa sile, mo si n so fun Sunday Igboho naa pe ko deyin leyin Ojogbon Banji Akintoye, nitori ko sona ninu Oodua to n polongo kiri.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp