
“Bi o ba wa ninu awọn obinrin to n wọ ṣokoto, tabi awọn aṣọ ọkunrin, o da ju pe inu ina lo n lọ.” Ọkunrin ajihinrere tẹẹ n wo aworan rẹ yii lo sọrọ bẹẹ.
Orukẹ rẹ ni Victor Edet, kii ṣe ọmọ Yoruba o, ohun to sọ fawọn eeyan lori ẹrọ ayelujara facebook rẹ niyẹn.
O ni, otutu to wa nilẹ Yuroopu, Amẹrika, ati Kanada ko yẹ ko jẹ anfaani fawọn obinrin lati maa wọ ṣokoto, bii ọkunrin. O tun ni satani lo gbe ṣokoto wa saye kawọn obinrin le maa wọ ṣokoto, ki wọn lọ sinu ina.
Ẹ gbọ, ṣe bẹẹ ni?
