Iroyin to n te wa lowo fi han pe Oladipupo Adebutu ati Segun Sowunmi, awon mejeeji ti won n ja si akoso egbe oselu PDP nipinle Ogun ti pari ija laarin ara won.
Lonii ni Segun Sowunmi gbe oro naa sori ero ayelujara re. O ni; “Ko si ologbon okunrin ti i wo ile baba re ko daru, paapaa ni onitohun ba lanfaani atije ki alaafia joba. Mo sabewo sile Onarebu Ladi Adebutu lonii ni Iperu, lati wo bi a se le wa ojuutu si wahala to n sele legbe oselu PDP l’Ogun. Mo gba lati je agba ninu yara naa,” lohun ti Otunba Segun Sowunmi.
Bee o ba gbagbe, laipe yii ni ileejo fagile Ladi Adebutu gege bi oludije fun ipo gomina ipinle Ogun, labe asia egbe oselu PDP.

