Zainab Omowunmi

 

‎Ẹni to jẹ igbakeji gómìnà nipinlẹ Eko to tun jẹ adijedupo si ipo gómìnà labẹ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú  All Progressives Congress APC ninu idibo ọdun 2027to n bọ yii, Obafemi Hamzat,   ti sọ̀rọ̀ nipa ṣunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ̀ ti n ma n waye nilu Eko, oni àṣá ati ami idanimọ ni, ki ṣe àrùn tabi ìṣòro.

‎

‎Ninu ọrọ Hamzat, o ni lati ọjọ alayetidaye ni súkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ti n fi igba gbogbo waye ni Eko, ki si ṣe nitori pe òpópónà o dara tabi  nkankan o, oni iṣẹda ilu Eko ni ọrọ súkẹrẹ-fàkẹrẹ naa.

‎

‎Hamzat ni, àwọn àgbègbè kan wa nilu Eko to jẹ pe tí eyan ba de ibẹ ti ko si súkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀, o ye ki eyan wo pe kilo ṣẹlẹ̀, eyi ni pe ami idanimọ ni ṣunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ̀ n’ilu Eko.

‎

‎Ninu ọrọ rẹ, o fi ori afara kẹta Mainland ṣe àpèjúwe, oni tí eyan ba de ori afárá yii ni ago mẹfa irọlẹ, yoo mọ pe súkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ki ṣe iya fun àwọn aralu Eko, eto aye lo jẹ.

‎

‎Hamzat ṣe àfikún pe súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ tun ṣe ìrànlọ́wọ́ fun eto ọ̀rọ̀ àje ipinlẹ naa nítorí onírúurú karakata ni ma n waye ni akoko ti ọkọ ba duro.

‎

‎Koda oni àwọn elere agbelewo naa ma n lo súkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ lati ṣe àpèjúwe bi eto ọ̀rọ̀ aje ilu Eko ti dara to.

‎

‎

‎Hamzat ni ẹnikẹ́ni to ba ri súkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ilu Eko gẹ́gẹ́bí wàhálà ti gbàgbé orírun ilu naa ni nítorí lati ọjọ to ti pẹ nilu Eko ti ma n fi ìgbà gbogbo wa niru ipo naa.

‎

‎O wa sọ di mimọ pe ilu Eko ki fi eto abo àwọn eyan rẹ ṣeré o, oni àwọn eyan le pọ lotọ ṣùgbọ́n abo to peye wa fun gbogbo wọn.

‎

‎Bakanna ni ìjọba n fi igba gbogbo ṣe ìrànlọ́wọ́ to yẹ si eto ọ̀rọ̀ aje ipinlẹ naa lati jẹ irọrun fun awọn aralu.

‎

‎

‎

‎

‎

‎

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp