Ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Olusola Sanwo-Olu, ti gbóríyìn fún ileewe St. Gregory’s College fún ipa tí ilé ẹ̀kọ́ náà ti ń kó nínú ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́, ìkọ́ni nípa ìwà rere àti dídàgbàsókè àwọn aṣáájú láti ìgbà pípẹ́.
Gómìnà náà ṣàpèjúwe ileewe naa gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó ti kó ipa ńlá nínú ìtàn ẹ̀kọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó àti Nàìjíríà lápapọ̀.
Sanwo-Olu sọ èyí ní ọjọ́ Àbámeta, Satide, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹsán, ọdún 2026, níbi Grand Reception and Lifetime Achievement Awards tawon akekoojade ileewe St. Gregory’s ṣètò, tó wáyé ní Naval Dockyard, Ahmadu Bello Way, Victoria Island, Èkó.
Nígbà tí ó ń ṣojú fún Gómìnà níbi ayẹyẹ náà, olórí awon osise Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Bode Agoro, sọ pé St. Gregory’s College ti ń fi àpẹẹrẹ hàn nípa bí ẹ̀kọ́ tó ní ìdílé rere ṣe lè yí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn padà.
Ó ní àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tó níye ní oríṣìíríṣìí ẹ̀ka, pẹ̀lú Iṣẹ́ Ìjọba, òwò, ẹ̀kọ́ gíga, iṣẹ́ ọnà àti àwọn iṣẹ́ amọ̀ja mìíràn.
Gómìnà Sanwo-Olu tún yìn ìpinnu ilé ẹ̀kọ́ náà láti dá eto iranwo ti won pe ni Endowment, Perpetual and Infrastructure Development Fund sílẹ̀, èyí tí ó ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ tó yẹ fún ìtọ́jú àti ìmúgbòòrò ogún tí St. Gregory’s College ti kọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Gẹ́gẹ́ bí Gómìnà náà ṣe sọ, owó ìdásílẹ̀ náà yóò lè jẹ́ ọ̀nà fún fífún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìrànlọ́wọ́ ẹ̀kọ́, kí wọ́n lè ṣe àtúnṣe àti ìdàgbàsókè àwọn ohun èlò ilé ẹ̀kọ́, ṣe àtìlẹ́yìn fún ìmọ̀ tuntun, àti láti mú kí ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ náà tẹ̀síwájú sí ipele tó ga.
Níbi ayẹyẹ náà, Olórí Iṣẹ́ Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀gbẹ́ni Bode Agoro, náà gba Lifetime Achievement Award, gẹ́gẹ́ bí ìyìn fún àwọn àṣeyọrí rẹ̀, iṣẹ́ ìsìn tó yàtọ̀ àti ipa tó ti kó sí àwùjọ.
A tún sọ pé ẹ̀bùn náà jẹ́ ìmọrírì fún bí Agoro ṣe ń jẹ́ kí orúkọ St. Gregory’s College ní ọlá àti iyì, nípa fífi àwọn ìlànà àti àṣà rere tí ilé ẹ̀kọ́ náà dúró fún hàn nínú iṣẹ́ rẹ̀.
Àwọn mí ìn tí wọ́n tún gba ẹ̀bùn níbi ayẹyẹ náà ni adari ileefowpamo agba ile wa, Central Bank of Nigeria, Dókítà Olayemi Cardoso; oga awon olopaa patapata, Ọ̀gbẹ́ni Olatunji Disu, psc, FCIPM; Ọba Abdulwasiu Omogbolahan Lawal, CON, Abisogun II, Onírù ti Ìrùland; Ọba Mobadenle Obalade Oyekan, Oníládò ti Iládò; Ọba Abdulsemiu Orimadegun Kasali, Adegboruwa ti Igbogbo; Oloye Anthony Asuquo Ani, CON; àti Dókítà Abimbola Ogunkelu, MD, FACA, FWACP, FNCS, lára àwọn míì.
Ayẹyẹ náà tún jẹ́ àǹfààní láti ṣe àfihàn ipa tíleewe St. Gregory’s College àti àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ti ń kó nínú ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́, ìwà àti aṣáájú ní Nàìjíríà.