…Ó ní ìjọba ń ṣiṣẹ́ láti mú kí Eko mọ́ tónítóní
Ìyáwo gomina ipinle Eko, Ìyáàfin Ibijoke Sanwo-Olu, ti bẹ̀ àwọn aráàlú Eko pé kí wọ́n ní sùúrù pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ náà, bí ìjọba ṣe ń gbìmọ̀ àti ṣiṣẹ́ láti wá ojútùú sí ìṣòro ìdọ̀tí tó ń dojú kọ ìpínlẹ̀ náà.
Ìyá Àkọ́kọ́ sọ èyí ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, nígbà tó kópa nínú ìgbékalẹ̀ ìmọ́tótó àyíká tó máa ń wáyé lóṣooṣù ní Mafoluku, nijoba ibile Oshodi/Isolo.
Ó kópa nínú eto náà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ láti ileese to n bojuto imototo, ati ileese kole kodoti iyen, Lagos State Waste Management Authority (LAWMA), àti Olùdámọ̀ràn Pàtàkì fún Gómìnà lórí Ọ̀rọ̀ Àyíká, Olùkúnlé Rotimi-Akodu.
Ẹgbẹ́ náà tún ṣàbẹ̀wò sí agbegbe Ajibulu, Oluyeye, Olowora, Eweje, Ayinde àti Ola-Ore, níbi tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò bí àwọn aráàlú ṣe ń bójú tó àyíká wọn.
Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, Ìyáàfin Sanwo-Olu bẹ̀ àwọn aráàlú pé kí wọ́n ní sùúrù, ó sì ṣàlàyé pé ìjọba ń ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó ní gbogbo ìgbà.
Ó ní, “Èmi ń bẹ̀ àwọn aráàlú Eko pé kí wọ́n ní sùúrù. A ṣì ń ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀. Gbogbo wa la ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti rí i dájú pé Eko mọ́ tónítóní.”
Ó fi kún un pé ìgbékalẹ̀ ìmọ́tótó àyíká tó máa ń wáyé lóṣooṣù náà jẹ́ ọ̀nà láti máa rán àwọn aráàlú létí nípa pàtàkì tó wà nínú mímọ́ àyíká.
Ayá Àkọ́kọ́ náà tún rọ àwọn aráàlú láti máa pín ìdọ̀tí sí oríṣiríṣi kí ó tó di pé wọ́n kó wọn lọ.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, díẹ̀ lára àwọn ìdọ̀tí tí wọ́n rí nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn igo, ìdọ̀tí gbígbẹ àti ìdọ̀tí tó ní omi nínú.
Ó ní ó ṣe pàtàkì kí àwọn aráàlú máa yà àwọn ìdọ̀tí wọ̀nyí sí ara wọn kí iṣẹ́ kíkó àti ṣíṣàkóso wọn lè rọrùn.
“A rí i pé a nílò láti túbọ̀ kọ́ àwọn aráàlú nípa èyí, nítorí pé díẹ̀ lára àwọn ìdọ̀tí tí a rí lónìí ni àwọn igo, ìdọ̀tí gbígbẹ àti ìdọ̀tí tó ní omi. A nílò láti yà wọ́n sí ara wọn kí ó lè rọrùn láti ṣàkóso wọn nígbà tí wọ́n bá ti kó wọn,” ni ó sọ.
Ó fi dá àwọn aráàlú lójú pé ìjọba máa tẹ̀síwájú nínú àwọn ìgbésẹ̀ tó ń gbé láti mú kí ìpínlẹ̀ Eko mọ́, tó sì tún rọ gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè láti ṣe ipa tiwọn nínú mímọ́ àti dídáàbò bo àyíká.

