
Gomina Babajide Sanwo-Olu ti sọ ọ di mimọ pe ẹnikẹni to ba tako ofin tijọba ti la kalẹ nipa arun Korona to n ja lọwọ lawọn maa fi jofin.
O sọrọ yii nigba to n kede fawọn eeyan pe oun ti bọ lọwọ arun naa.
Bii ọjọ mẹrinla, iyẹn osẹ meji ni gomina fi wa lahamọ nitori arun yii, tawọn olutọju si n tọju rẹ.
Sanwo-Olu ni, o ti deewọ lati lọ sibikibi, paapaa awọn ibi ti ero ba pọ si, la i lo ibomu, bẹẹ lo si tun fagile gbogbo ipejọpọ to maa n waye lasiko ọdun, paapaa aisun ọdun, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
