Zainab Omowunmi

 

Igi ńlá wo, kọ̀wé ké, awùjọ òṣeré tí pàdánù ọkàn lara awọn gbongbo ńlá wọn, ọkan pàtàkì lára àwọn oṣere tíata tí irawọ rẹ tán yanranyaran lo tí di olóògbé.

 

Agba oṣere nnì, Taiwo Hassan tí ọ̀pọ̀ awọn olólùfẹ́ rẹ mọ sì Ogogo ọmọ kulodo lo tí jáde láyé lẹni ọdún mẹrindinladọrin(66) lẹ́yìn arẹ aarun jẹjẹrẹ.

 

Ọjọ́ àìkú òní yìí, ọjọ kẹtalelogun, oṣù kẹjọ ọdun 2026 yìí ni olóògbé náà jáde láyé, iyalẹnu ńlá ni ikú rẹ jẹ fún ọpọ awọn olólùfẹ́ rẹ nitori òun ti a gbọ̀ ni pé iyatọ tí ń wá.

 

Fọ́nrán kan tó wà kakiri orí ayélujára, lo ṣe àfihàn ọkàn lára ọmọ olóògbé náà, Kira Taiwo, inú fọ́nrán yìí ni Kira tí fi omi ojú sọ pé baba òun ti di olóògbé.

 

 

Tẹ ó bá gbàgbé, ṣáájú àkókò yìí, Kira àti Haleemah lọ kede pé baba awọn, Ogogo ni aarun jẹjẹrẹ tó sì ti wá ní ipele kẹrin.

 

 

Ṣáájú kí ọlọjọ tó dé, gbajumọ oṣere Yoruba ni Ogogo tó sì jẹ àgbà ọjẹ tí ọ̀pọ̀ araye ń fẹ.

 

Ogogo fi iṣẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí oṣere tíata gbe àṣà àti ìṣe ilẹ Yoruba lárugẹ.

 

Ọdún 1959 labi àgbà eléré náà tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ tíata ni ọdun 1980.

 

 

Ọ̀pọ̀ ara, ọrẹ àti olólùfẹ́ lọ tí bọ sì ori ayélujára láti daaro ikú bàbà náà tí wọn sì ń ròyìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni re.

 

 

 

 

 

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp