Zainab Omowunmi
Kọmíṣọ́nà tẹ́lẹ̀ri nipinlẹ Ogun àti olùdíje gómìnà ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Semanko Abayomi Hunye, tí fìdí rẹ múlẹ̀ pé òun ṣí ń díje dupò labẹ asia ẹgbẹ́ òṣèlú APC, òní ahesọ ọrọ lásán ni ìròyìn pé òun kò dijedupo gomina labẹ asia ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress mọ.
Hunye sọrọ náà di mimọ ni ọjọ Abamẹta yìí ni akoko tó ń bá awọn oniroyin àti àwọn alatilẹyin rẹ sọ̀rọ̀ níbi tó ti ṣe àfihàn ẹniti yoo jẹ igbakeji rẹ.
Hunye ṣe àfihàn Otunba Abayomi Odunowo gẹgẹ bí igbakeji rẹ ninu idije sì ipò gomina ipínlẹ̀ Ogun ni ọdún 2027.
Nínú ọ̀rọ̀ Hunye, oni òhun kò fi ọwọ sì idibo abẹle tó gbé adije dupo gomina tí ẹgbẹ́ APC fọwọsi, ìyẹn ṣẹnetọ Solomon Olamilekan Adeola tí ọ̀pọ̀ mọ sì Yayi kalẹ.
Ó fìdí rẹ múlẹ̀ pé oun ti gbé ọrọ náà lọ sí ileẹjọ, òní kí ẹnikẹni má gbọ ọrọ ahesọ pé òun kò dijedupo labẹ asia ẹgbẹ́ APC mọ.
Ó rọ àwọn alatilẹyin rẹ pé kí wọn lọ fi ọkàn balẹ nítorí dídùn ni ọsan yóò soo ni ile ẹjọ, òní òun ni ìdánilójú pé òun yóò jawe olubori.
Nínú ọ̀rọ̀ Hunye òní, “kí àwọn ẹ̀yán lè mọ pe mo ṣí wá nínú idije ni mo ṣe ṣe àfihàn igbakeji mi”.
Hunye ṣe àpèjúwe Otunba Abayomi Odunowo gẹ́gẹ́ bí olódodo ẹ̀yán àti ẹni tó nifẹ ipinlẹ Ogun, òní òun ni igbagbọ pé àwọn yóò jọ ṣiṣẹ fún igbega Ìpínlẹ̀ náà.
Bakanna lọ tún sọ síwájú pé ọmọ Yewa pọnbele ni òun ti ko si àríyànjiyàn nínú.
Tẹ ó bá gbàgbé ibo 304,055 ni sẹnetọ Solomon Olamilekan Adeola fi jawé olubori nínú idibo abẹle ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
