Nojeem Ege
Oluwatobiloba Amusan ni odomode elere ori papa ile wa tirawo re n tan lowo kaakiri gbogbo agbaye, koda ileese nla kan ti yan omobinrin naa gege bi asoju fun ileese won. Aipe yii ni won safihan re fun awon oniroyin. Plug Sports, loruko ileese naa.
Sugbon kisu too diyan, a gun isu lodo loro omobinrin naa, kii soni ni ise ati di irawo ilumo-on-ka lagbaaye ohun bere. Koda nigba tirawo re fee bere si i tan, ipo kerin lomobinrin maa n se saa, amo ko je ki irewesi okan ko mu oun rara, o saa gbagbo pe lojo kan loun maa bori, oro naa si ti ri bee.
Lojo kan, ojo kejo, osu kokanla, odun 2016, ni nnkan bi odun merin seyin bayii, ni nnkan bii aago meje aaro, bi Tobi se ji lori beedi re bayii lo gba foonu re mu, lo ba lo sori ero ayelujara re ti won n pe ni twitter.
Ohun ti Tobi si ko sibe naa ni pe; “Won o ni gbagbe mi, loooto won ko ti i mo mi bayii, n o ni saare, titi n o fi jawe olubori.” Ohun ti Tobi ko sori ero twitter re laaro ojo naa niyen.
Nigba to tun di odun 2020, Tobi tun gbe foonu e, lo ba gba ori ero twitter lo, ohun to ko sibe naa ni pe, “Koosi mi ko mi pe nigbakugba ti mo ba wo inu yara to kun fun opolopo eeyan, paapaa awon akegbe mi taa jo n ta kangbon lori papa, ki n ri ara mi gege eni to dara julo laaaarin gbogbo won, ati paapaa eni to le sare ju lori papa lagbaaye.”
Leyin odun meji ti Tobi ko awon akole yii nko, ko seni ti ko mo bayii pe omobinrin naa n sa yati lori papa. Koda, kani kii se ti afefe ti won lo fa omo naa seyin die lori papa, a baa maa so pe ko ti i seni to sa iru ere bee lori papa, ninu itan ere idaraya.
Tobi ni omo orile-ede Naijiria akoko to maa gba ami-eye elere ori papa ti won n pe ni Hurdles to mo ere sa julo. O fagile itan ti Arabinrin Jasmine Camacho-Quinn fi sile tele.
Ohun tawon eeyan n beere lowo ara won latigba tomobinrin yii ti gba ami eye yii naa ni pe tani Tobi Amusan?
Ibere Tobi Amusan
Omobibi ilu Ijebu Ode nipinle Ogun ni Tobi Amusan, a bi i lojo ketalelogun, ou kerin, odun 1997. Merin si ni gbogbo omo tawon obi re bi. Ohun ti Asejere gbo ni pe akekoo ileewe lawon obi re mejeeji.
Eyin naa ti mo iru omo teeyan ba to nile tisa, e ti mo biru won ti maa n ri. Yato si ohun to ba ti je mo iwe omo naa, ko sohun tiru awon obi bee fee gbo latenu omo won rara, ko si bo ti wu ko dun to.
Ohun to mu ko yato die fun Tobi ni pe ati baba ati iya re, awon obi mejeeji sere ori papa, bo tie je pe baba ko tie fe komo oun sunmo idi ere ori papa, yato si pe ko gbajumo iwe re, sibe Iya Tobi duro ti i gbagbaagba, iya naa si se e debi pe okan ko ni di ekeji lowo rara.
“Awon nnkan ti mo maa n saaba se ni ki n sun, ki n jeun, ki n kawe mi, ohun ti mo maa n se lojoojumo niyen lojo aye mi,” lohun ti Tobi so fun awon oniroyin ile okeere nigba ti won ni ko so iriri re.
Tobi tun so fun awon oniroyin pe nigba ti mama oun farapa lo sese yee sare ori papa, nitori elere ori papa bii toun naa ni, bo tie je pe boolu alafowogba ti won n pe ni Volleyball ni baba oun n gba ni tie. Sugbon, ojoojumo lawon mejeeji maa n kilo fun un pe ko ma se nnkan to ma lodi si iwe to n ka.
Bi Tobi se bere boolu alafesegba
Ileewe giga Our Lady of Apostles Secondary School, niluu Ijebu Ode nipinle Ogun naa ni Tobi ti kawe girama, ibe naa ni irinajo yen ti bere. Sanko ni won maa n saaba pe e, nitori omo kan ti ko fi bee lara pupo ni.
Ohun ti opo eeyan ko mo ni pe boolu alafesegba ni Tobi fi bere irinajo ere idaraya re, sugbon o feran ko maa sare kiri lori papa isere. Eyi lo mu ki won mu u lo si odo akoni-mo-on-sa kan to mo bi a ti n koni bi a ti n sare lori papa. Ninu idanrawo ti won se fun Tobi, oun lo se ipo kinni. Bo se bere irinajo re lori papa niyen.
Kia Tobi ti bere si i gba ami eye loko etile, gbogbo awon idije ti won se nile wa, paapaa eyi to waye niluu Warri fun awon odo lodun 2013, ipo keji lo se. Oun atawon elere bii Ese Brume ati Divine Oduduru ni won jo dije niluu Warri nigba naa.
Lodun 2014 ti won lo fun idije agbaye, Tobi wa ninu awon to ye ko lo fun idije naa, sugbon kete ti won fee rinrinajo naa ni won yo oruko re kuro ninu awon to maa lo sare onigi taa n pe ni Relay. Ohun to fun un lanfaani ati dije fun ere hurdles, o si se ipo keji.
O tun lo sile Botswana lodun 2015, o se ipo kinni nibe, bee lo si tun se ni idije ere idaraya ile Afrika to waye ni Brazzaville, Congo.

