← Back

Thank you for your response. ✨

 

Ile ẹjọ majisireti kan ni Umuahia nipinlẹ Abia ti ju Pasitọ Uche Arua Kalu si ẹwọn ọdun mẹwa pẹlu iṣẹ aṣekara latari pe o fi ipa ba ọmọde binrin ọmọ dun mẹrin ni ajọṣepọ.

 

Adajọ ko fi aye sisan owo itanran kankan silẹ fun Kalu ọmọ ogoji (40) ọdun to fi agidi gun ori ọmọdun mẹrin naa ni agbegbe Amaogudu Abiriba nijọba ibilẹ Ohafia nipinlẹ Abia.

 

Onidajọ Onuoha U.C ni iwa buruku ti eeyan ko gbọdọ ma ba ni ọwọ ẹnire gba ni Kalu hu nitori nA ko lọ fi ẹwọn gbara lai si ẹbẹ ninu ọrọ naa.

 

Lasiko igbẹjọ, ọlọpa to wa nidi iwadi ẹjọ naa, ASP Iweajunwa jẹ ko ye adajọ pe Kalu tun pa irọ fun awọn pe oun ko wu iwa naa.

 

Oni ni oṣu kejila ọdun 2024 ti igbẹjọ naa kọkọ bẹrẹ ni Kalu ti jẹwọ pe oun wu iwa naa, oun to wa mu tun yari pe oun ko ṣe ni koye oun, oni tẹlẹri o ti sọ pe oun ko mọ oun to jẹ ki oun ṣe bẹ pẹlu ọmọ naa, ni gba ti igbẹjọ ti n lọ lo wa tun ni oun ko ṣe.

 

Sugbọn ọlọpa Iweajunwa fi iwe ti wọn fi gba ọrọ lẹnu rẹ ni igbati iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ̀ ti osi ni oun ṣe fi han adajọ ni ọrọ ba pesi jẹ.

 

Agbẹjọro fun ijọba salaye pe ki eniyan to le jẹbi ifipa bani lo, oni ikan mẹta ni o gbọdọ waye, akọkọ ni pe ọmọ ti wọn balo gbọdọ jẹ ọmọdé, ẹni ti wọn fi ẹsun kan gbọdọ ba ọmọ naa lo ati pe ẹni ti wọn balo ko gbọdọ ni ọwọ si ibalo oun.

 

Agbẹjọro fun ìjọba ni ti gbogbo eyi ba waye, afẹsun kan ti jẹbi ẹsun oju ewe keje abala kini ati ikeji ti ofin iṣẹ si eniyan ti ọdun 2019, 7(1)(2) of the Violence Against Persons Prohibition Law 2019.

 

Labẹ ofin naa, ẹjọ ẹwọn lailai ni wọn yoo dafun, oni gbogbo awọn oun ti awọn ka silẹ yii ni Kalu jẹbi rẹ nitori ẹ, o rọ adajọ ki wọn da ẹjọ na bo ti tọ ati bo ti yẹ.

 

Iya ọmọdebinrin naa, to jẹ opo ra ọwọ ẹbẹ si ile ẹjọ pe ki wọn ma ṣe jẹ ki iya jẹ oun gbe nitori oun ko ni ọkọ.

 

Oni Pasitọ Kalu tan ọmọ oun wọlé nitori ibaṣepọ to dan mọran to wa ni aarin awọn ni, ṣe ti oun ba mọ pe ẹni bi ni, ṣe oun a wa ba ṣe.

 

Oni oun lọ ibiṣẹ ni oun de ti oun ba ọmọ nibi ti o sun si ti ẹjẹ si wa ni ara rẹ, nigba ti awọn de ile iwosan ni ọmọ to salaye oun to ṣẹlẹ.

 

Oni Pasitọ Kalu kọkọ yari mọ oun lọwọ, nigbati ẹgbọn baba ọmọ naa fi ọlọpa gbe lo to jẹwọ.

 

Lẹyin gbogbo atotonu yii ni adajọ ba bu ountẹ lu ẹwọn ọdun mẹwa, oni ki Kalu lọ fi sokoto penpe roko ọba.

 

 

 

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp