Ijoba ipinle Eko ti seleri pe gbogbo ise ti awon jogunba lawon maa pari ko too di pe Gomina Babajide Sanwo-Olu kuro lofiisi lodun 2027.

Olugbaninimoran fun gomina lori oro ise ode, Omowe Adekunle Olayinka ati ojugba re ni eka ise akanse, Olufemi Daramola ni won se bayii soro nigba ti won n ba awon oniroyin soro lopin ose to koja yii.

Olayinka so pe lara awon ise akanse to n lo lowo ni ileewosan awon omode to won n pe ni Massey to wa ni Eko, ati ileewosan to wa ni Ojo.

Awon mejeeji tun so pe ise akanse lo mu ki ipinle Eko je ibi akoko fun awon olokoowo lati wa se oro aje won, ati pe o je ona kan ti ijoba n gba mu ileri ati majemu ti won se pelu awon araalu se. O ni gbogbo awon ise ti won ti bere pata lawon maa pari ko too di opin saa naa.

Gege bi Daramola ni tie se so, lara awon ise to n lo lowo ni oju ona Lagos Lagoon, oju ona 7th Axial, oju ona Taiwo leba China Town ni Ojota, afara Shashalara re ni ti Union, Shomorin, Mortune, Adama Dania, Mohammed, Ayetoro, Ashipa, afara Ayobo-Igando, Alaaji Shekoni, Ijegun-Ijeagemo titi lo de LASU Iba. Awon ise akanse yooku tun ni ise ojuna Okota/Apapa-Oshodi, Awodi-Ora /Olodi, Ajeromi ati Amukoko/Ogbowankwo pelu Ajeromi.

Bakan naa lo tun menuba a pe ise ojuna ti ajo PWC ti gbese ti fee to egberun meta, iyen 2,702 roads ati pe ise si n lo lowo. Bee lo si tun so pe awon tun n wa ona mi in tawon le gba lati maa lo awon ohun eelo igbalode lati se atunse awon ise oju ona wa.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp