Ijoba ipinle Eko ati ileese adani kan ti a mo si Lagos Island Connect (LIC) ti setan ati seto ipate oja kan ti yoo waye lati ojo kerinlelogun si ojo ketadinlogbon, osu kokanla odun yii. Gbongan Tafawa Balewa to wa ni Onikan ni ipate oja naa ti fee waye.

Ninu ipade awon oniroyin to waye lopin ose to koja yii ni Alausa, komisanna fun eto oro aje nipinle naa, Abileko Lola Akande so fun awon oniroyin pe ipate oja naa je eyi to wulo fun eto isejoba Gomina Babajide Sanwo-Olu, eyi ti won pe ni T.H.E.M.E.S. Agenda.

Ipate oja naa ti won pe ni LI-BIZ-FAIR je eyi ti won seto lati fi gbe awon olokoowo keekeeke, ati awon onise adani laruge ninu eto oro aje won, paapaa awon odo ati lati mo anfaani ti enikookan won ni ni agbegbe Isale Eko.

Akande ni eto ipate oja naa se pataki nitori yoo da lori awon olokoowo keekeeke ati awon aladaani paapaa ti won wa ni Isale Eko ati agbegbe re lapapo.

Oludasile ileese Lagos Island Connect (LIC), to n sagbateru ipate oja naa, Abileko Yemisi Ransome-Kuti ni ileese oun gbe eto naa kale lati koju awon ipenija to maa jeyo fun awon olokoowo lojo iwaju nipinle Eko.
Bee lo dupe lowo ijoba ipinle Eko fun akitiyan won lori awon olokoowo keekeeke, ati iranlowo ti won n fun won nipinle naa. O ni, erongba ileese oun ni lati gbe ipate oja naa lo si gbogbo ijoba ibile ati agbegbe idagbasoke to wa kaakiri ipinle naa, lati mu ki igbe aye awon onise owo ati olokoowo keekeeke tubo gberu si i.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp