Zainab Omowunmi
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti yọ olori awọn akọni mọ gba wọn, Ruben Amorim nipo, wọn ni ko ka oju òṣùwọ̀n to ko si yẹ leni ti yoo ṣe aṣaju awọn akọni mọgba ikọ naa.
Ọjọ́ Aje ọsẹ yii to jẹ ọjọ́ karùn-ún oṣù kinni ọdun 2026 ni wọn yọ Akọnimọgba Ruben Amorim to jẹ ọmọ orile-ede Portugal nipo bi ẹ ni yọ jiga.
Ohun ti awọn alaṣẹ Old Trafford salaye ni wipe ko si ìlọsíwájú lati igba ti Ruben ti darapọ mọ awọn, oṣù kankanla ọdun 2025 to kọja yii ni Ruben ṣe darapọ mọ ikọ Man U gẹ́gẹ́ bi Akọnimọgba agba, ko i ti lo gbedeke oṣù mẹta pẹlu wọn ti wọn tun ti ni ko lọ rọ kun le.
Lori tabili idije Prẹmia ligi, ipo kẹfa ni ikọ Man U joko le, ti Ruben naa si fi aidunnu ọkàn rẹ han lẹyin idije wọn pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Leed United ti wọn gba ọmi ayo kankan.
Iwe royin Asejere ti tẹ ti le ko lati tun gbọ ẹni ti ikọ Manchester United yoo yan gẹ́gẹ́ bí akọnimọgba agba fun ikọ naa bi wọn ti n ṣe palamọ fun awọn idije to kan.

