Olori awon oloja ni agbegbe Mainland niluu Eko, iyen Alaaja Sikiratu Ejide Tiamiyu, ti gbogbo eeyan mo si Sikira Olobi ti jade laye. 

Aaro ojo Isegun, Tusde yii ni won kede iku Iyaloja naa, won jade laye leni odun merinlelogorin (84).

Sikira Olobi ni Iyaloja Oyingbo, bee ni won si tun je iyaloja jenera fun gbogbo ijoba ibile Mainland, l’Ekoo. 

Opo eeyan paapaa awon oloja ni won mo Sikira Olobi gege bi akikanju obinrin laarin awon olori oja nile Yoruba, ati ni orile ede yii. Ko fi oja re sere, bee ni won si sakitiyan alaafia ati irepo awon oloja, paapaa ni oja Oyingbo. 

Asejere gbo pe won ti sin mama naa, gege bi ilana Musulumi lonii niluu Ikorodu, l’Ekoo kan naa. 

By Asejere

Follow by Email
WhatsApp