Odomode aderinposonu ori ero ayelujara tirawo re n tan lowo nni, Debo Adedayo sugbon ti gbogbo eeyan mo si Mr Macaroni ti ke gbajare sita pe awon kan n dunkooko mo oun nitori awon oludije meji kan ti ko daruko.
Omokunrin naa soro naa lanaa lori ero ayelujara re, bo tie je pe ko daruko awon oloselu ti awon eeyan naa n ja fun ti won fi n dunkooko mo on.
Sugbon, opo eeyan lo mo pe Macaroni wa ninu awon odo lori ero ayelujara ti ko gba ti egbe oselu APC ati PDP, paapaa nipinle Eko.
O pe ti omokunrin naa ti n so pe gbogbo awon to lowo si bi awon olopaa se fi iya je awon odo lodun 2020 lasiko iwode ENDSARS, lawon maa tako pata lasiko ibo odun 2023.
Macaroni ni, lenu ojo meta yii lawon kan bere sii dunkooko mo oun nitori oun ko gba lati tele oloselu ti won fe, o loun ko si setan ati polongo fun iru eeyan bee. Awon to mo boro naa se n lo so pe Babajide Sanwo-Olu to je gomina ipinle Eko ati Bola Tinubu to je oludije fun ipo aare fun APC lomokunrin naa n ba wi.
“Laipe yii ni mo lo sodo awon obi mi, mo loo ki won, bi mo si ti setan ni mo bere si i fun awon eeyan lowo, gege bi mo ti maa n se, bee lobinrin kan waa ba mi, to si bere si i so pe ki lo de ti mi o tele oludije awon, mo ni mi o koriira oludije won, sugbon eni to ba maa tun Naijiria se lemi maa tele.
“Ohun ti mo kan maa gbo ni pe se lobinrin naa bere si i hale mo mi, to n so orisii oro si mi. Gbogbo ohun to so la ka sori fidio, nitori manija mi ati egbon mi wa lodo mi nigba to n so gbogbo oro naa.”
