Adeboye, Oyedepo, ati Kumuyi

Isin kan tawọn ọmọlẹyin Kristi kii fi ṣere paapaa nilẹ wa Naijiria yii ni isin aisun ọdun, eyi to maa n waye ni gbogbo ọjọ to ba gbẹyin ninu ọdun. Ṣugbọn gẹgẹ bi ikede ti waye lati ọdọ ijọba nitori arun Korona to ṣi n ja lọwọ, ọpọ awọn adari ileejọsin ni wọn ti fagile tọdun yii.
Aago mẹsan-an lọpọ ninu awọn ijọ maa n bẹrẹ ipade ọhun, wọn a si pari rẹ ni aago mejila si aago kan. Ninu isin yii lawọn eeyan ti n gbadura, ti wọn si n woju Oluwa fun ọdun tuntun, asiko naa tun ni awọn ojiṣẹ Ọlọrun tun maa n sọ nipa ohun to maa ṣẹlẹ ninu ọdun naa.
Ipinlẹ Ogun, Eko, Ekiti, Ọṣun ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti fagile aisun ọdun wọn. Koda, ṣe ni ipinlẹ Ondo fi dandan le e pe ẹnikẹni to ba ṣe iṣọ oru tabi isin aisun ọdun kan, ẹwọn ni yoo ti ke hapi niu yia, ẹ ku ọdun.
Eyi lo fa a ti olori ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye, fi sọ lọjọ Mọnde to kọja yii pe aago mẹfa irọlẹ nipade naa maa bẹrẹ, ori ẹrọ ayelujara ni wọn si ti maa wo o.
Bẹẹ lọrọ ri lọdọ olori ijọ Mountain of Fire and Miracles Ministries, iyẹn Ọmọwe Daniel Olukọya. Aago mẹsan-an si mọkanla ni isin tiwọn fi maa waye.
Ni ijọ Winners’ Biṣọọbu Oyedepo ti sọ pe aago mẹfa si aago mẹjọ nipade ọjọ naa yoo fi waye. Ṣugbọn ijọ Deeper Life, ti Alagba Williams Kumuyi jẹ adari rẹ ti sọ pe isin naa maa waye, lati aago mẹwaa, ṣugbọn lẹka-jẹka ni yoo ti waye.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp