Ileefowopamo ile wa nni, Fidelity Bank ti kede ere repete ti banki naa pa wole lodun yii, yato si eyi to wole lodun to koja.

Ohun ti Asejere gbo ni pe owo tiye re le ni Aadofa bilionu naira, iyen N110.992 ni won pa wole lodun yii, lai ti i yo owo ori rara.

Bee lodun to koja, iye ti banki naa pa wole ko ju bilionu mejidinlogoji, iyen N37.792 billion, lasiko yii kan naa lodun to koja.

A gbo pe aseyori nla yii ni i se pelu awon ohun otun ti awon adari banki naa gbe wole, awon owo ti won n pa wole, ati ele ti awon onibaara n san loorekoore.

 

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp