Dangote atawon orebinrin re

Parakoyi oniṣowo ilẹ wa nni, Aliko Dangote ti gbe ọrẹbinrin rẹ atijọ, Autumn Spikes lọ sileẹjọ nilẹ Amẹrika, nitori awọn aworan kan ti ọmọbinrin naa ju sori ẹrọ ayelujara laipẹ yii, eyi ti ko dun mọ ọn ninu.
Iroyin ti Aṣejere gbọ ni pe ṣe ni ọmọbinrin yii gbe fọnran kan nibi ti oun ati Dangote ti n gbadun ara wọn, sori ẹrọ ayelujara. Ninu fọnran naa, ni wọn ti n ba ara wọn ṣere ifẹ lori bẹẹdi, ti ọmọbinrin ara ilẹ Amẹrika naa si n fi foonu rẹ ṣere.
Bakan naa lo tun gbe awọn aworan Dangote sita, nibi ti o ti n sọkalẹ ninu yara ikọkọ ti ko yẹ kẹnikan ri rara, bo tiẹ jẹ pe gbogbo awọn aworan yii lọmọbinrin ọhun pada ko kuro lori ẹrọ ayelujara rẹ.
Ṣugbọn, ọrọ naa ko dun mọ Dangote ninu, o ti wọ ọrẹbinrin rẹ yii lọ si kootu, niluu Florida, to wa nilẹ Amẹrika, o si ni ki ileẹjọ gba ẹgbẹrun lọna ọgbọn foun lọwọ ọmọbinrin naa tori awọn aworan oun to gbe sita, eyi to ti mu ipalara wa foun.
Autumn, iyẹn ọmọbinrin gan an lo sọrọ naa sita fawọn araye gbọ, o ni, Dangote ti gbe oun lọ sileẹjọ, tori o fẹẹ pa oun lẹnu mọ, ko si le ṣe bẹẹ, tori oun nifẹ ẹ ni. O ni, o ti le lọdun mẹsan-an bayii toun atiẹ ti n jọ n wọle wọde.
Ko sẹni to le sọ pe oun mọ nnkan nipa igbesi aye Ọgbẹni Dangote n gbe, ọkunrin naa kii ba awọn oniroyin sọrọ aṣiri tabi ọrọ ifẹ rẹ pẹlu awọn obinrin rara, bo tiẹ jẹ pe o lawọn obinrin ti wọn ti bimọ fun un.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp