
Ki n tiẹ kọkọ gbee si i yin leti na laiṣe ibọn, ọfọ nla lo ṣe Adisa koda lọjọ ti wọn wa sọ fun un laarin ọja pe baba rẹ ku labule kinni ọhun ko wọọ lara to bẹẹ. Bawo lẹyin tiẹ ṣe fẹ ko ri, ẹni to ti yaju si gbogbo awa kọmiti ọja, ko tun fi mọ nibẹ o, Iwa aibikita lo hu si iyalọja nigba to tun ṣe afojudi si Babalọja tuntun. Ki n ma parọ fun yin, ko si ibi ti alakọri abara giọgiọ ara rẹ fojusi lọjọ iwuye babalọja wa tuntun. Loootọ ko si ọrọ ariwo nibẹ,wọọrọwọ la ṣee lati pa ofin to rọ mọ ajakale arun covid-19 mọ gẹgẹ bi alakalẹ ijọba ṣugbọn sibẹ pẹpẹyẹ pọnmọ nisọ eleso, ṣẹyin naa mọ pe nnkan maa n kangun si awọn kan ju awọn kan lọ.
Alaaji Ọlọhungbẹbẹ ni Olori awọn eleso, oun naa lo tun jẹ baba ọja tuntun, o wa ja si pe tiẹ di meji lọdọ awọn eleso niyẹn koda aṣọ oriṣii meji ni wọn mu, bo tiẹ jẹ pe iwaju isọ onikaluku ni faaji ti n ṣan ṣugbọn ohun kan to daju ni pe o han gbangba si awọn onibara lọja Aṣejere lọjọ naa pe faaji n ṣan koda ariya naa fẹẹ ma lopin fun awa taa si nidii ọtẹ toripe ṣe ni Adisa ka guọ bi ẹni ti ọba rọ loye to n wo bi nnkan ṣe n lọ. Iyẹn ni mo fi pinnu pe ki Ọlọrun ma jẹ ki n ri nnkan ti mo maa fi ba wọn gbe omi ọtẹ kana nitemi’, ha ọjọ yẹn ko daa fun Adisa rara. Loootọ loun naa ba wa wọ aṣọ ankara taa mu o toripe ko sẹni to tii rọọ loye bayii ṣugbọn aṣọ yẹn ko yee rara, ṣe lo dabi igba ti eeyan wọ aṣọ sọrun igi ọparun, tẹyin naa ba ri ara tawa taa si nidii ọtẹ fi ankara yẹn da soro a gbee yin lọ, koda ohun la tun fi ran aṣọ ibomu ni gbogbo ẹ ba kuku ṣe rẹgi, aṣe wahala rampẹ a maa mu ẹjẹ eeyan gbẹ! Lai ṣaarẹ Adisa yọ bi abẹla ajoku kọda awọn ọmọọṣẹ rẹ gan ko ri tiẹ ro.
Awọn Ọmọga, Jamiu ati Tayelolu ni wọn ṣe alabojuto bi gbogbo nnkan ṣe gun rege bi idodo ẹfọn. Ọlọgbọn ni babalọja wa tuntun, wọn ni ka ma fi iwa rẹ bẹẹ wo toripe a o le fẹ iru wọn ku lawujọ. Alaaji Ọlọhungbẹbẹ gan ni wọn ranṣẹ pe Adisa nibi to wararo si afi bi ẹni pe o ti n reti ki wọn ranṣẹ soun tẹlẹ ṣe lo sare dọbalẹ siwaju babalọja to bẹrẹ sii bẹbẹ taanu taanu, ẹ woo aanu rẹ kọkọ ṣemi o, ṣugbọn ọmọkunrin naa ko ṣee ṣaanu jare, ko niwa bẹẹ ni ko lẹwa, o tun mọ bi wọn ṣe n da ina ọtẹ ṣugbọn ṣa o damiloju pe ko sẹni to maa fi ọkan tan kinni buruku rẹ mọ. Bi Adisa ṣe n ba babalọja sọrọ ni Jamiu n sọ fun un pe ko sun sẹyin lati pa ofin korona mọ, ṣe mo ranti sọ fun un yin pe babalọja ti gba Jamiu gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ rẹ ṣẹyin naa mọ pe ọmọburuku lọjọọre tiẹ.
Bi babalọja ṣe tete dariji Adisa yẹn ṣeni iyalọja diju patapata, wọn ni ọrọ rẹ ko ju bintin niwaju awọn mọ, mama sọ pe iku tii pani lọmọkunrin naa ati pe ṣeni igbesẹ iṣubu to gbe ṣi n bi awọn ninu toripe to ba jẹ pe o ri ọna lo ni, o daju pe iṣipopada maa ti de ba awọn bayii. Pako bayii ni Adisa n ṣẹju bii maalu to kofiri ọbẹ ṣugbọn sibẹ ejo lọmọkunrin naa ko ṣee nu ẹnu fun.
O ṣe diẹ tawọn akolẹ ti wọ inu ọja gbẹyin bẹẹ ni iṣoro pọ lo koda, ibomu di tulaasi toripe beeyan ko bo imu nitori koronafairoo yoo bo imu tori oorun ilẹ. Ṣugbọn lọwọ bayii Jamiu ni iṣoro Adisa toripe ko tiẹ fẹẹ ri i nitosi babalọja rara ni, wọn si tun ti sọ pe ko maa mojuto bi awọn akọlẹ ṣe maa tete maa wa kọlẹ toripe iyẹn naa jẹ iṣoro kan lọtọ, ara awọn nnkan ti Adisa maa fi n ṣe ọkọ awọn ale rẹ niyẹn toripe owo igbẹ kii run ni bayii.
Ija agba meji fẹẹ ṣẹlẹ o, Adisa n gbiyanju lati tun orukọ ara rẹ ṣe ninu iwe Alaaji Ọlọhungbẹbẹ ṣugbọn ọmọga yari o ni afi ka ranti owe adehun toripe gbogbo nnkan taa nilo lati mọ iru iru ti ọga oun n pa labẹnu loun tu sita toripe naa ipo rẹ gẹgẹ bi igbakeji ọlọpaa ọja loun fẹ. Ẹ gbọ ta lo maa fi inu tan Ọmọga to fi idi aṣiri Ọga rẹ hande. Emi o sọ fun un bẹẹ o, mo kan n roo ni ṣugbọn ọrọ naa gbero gidi.
Nnkan de o, awọn Hausa ti wọn wa lọja lawọn naa fẹẹ yan olori to jẹ ẹya tiwọn, ẹru ma ti pe nile kẹ, ṣe ọga meji le wa ọkọ kan naa ni. Ọrọ naa kii ṣe awada o, wọn miini ẹ ni o ṣugbọn awa naa ti da esi lẹta wọn pada fun wọn. Adisa tiẹ faraya ṣe oun kuku gbọ hausa daadaa ni tiẹ. Imu ẹlẹdẹ Adisa ma tun pada wọgba o.

