Asiko yii kii ṣe asiko teeyan n na gẹrẹ o koda ẹnikan ko ri tẹnikan ro nitoripe ṣe ni onikaluku gbajumọ ọja rẹ tori asiko perete la ni lati taja bayii. Ipolongo ibo to n lọ lọwọ lo fa a abi ẹyin o mọ pe awa ọlọja naa maa ṣe pupọ nibẹ, a gbọdọ jọ mojuto ọrọ naa ni o nitoripe ẹni to maa gori aleefa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ ati aarẹ orileede paapaa gbọdọ fi tiwa ṣe toripe a pọ niye iyẹn naa lo mu ki awa igbimọ ọja maa ṣe ipade leralera, ani a gbọdọ gbe ẹni taa fẹ ko wọle ibo yẹwo daadaa ki a to ta orukọ rẹ fun awọn ara ọja.

Ki n ma tiẹ sọrọ nipa Adisa, o yẹ kẹyin naa beere gẹgẹ bẹẹ ṣe mọ pe alajẹbanu ni, kosi ẹni ti kinni buruku abara giọgiọ rẹ ko le tẹle bo ba ti rowo gba nibẹ, ani o lọọ ṣa awọn kan jọ, o ni ki wọn tun maa wa ṣe mitiini kan niwaju isọ ẹran abi ẹyin naa o ri i pe o yẹ ki babaọja paapaa mojuto ọrọ ara rẹ, o jọ bi ẹnipe ipo rẹ ni Adisa ọwala n ranju mọ abi kin ni ka ti pe tẹni ti ko ni mọto to lọ n fojoomumọ to sile epo. O jọ bi ẹnipẹ babalọja paapaa mọ pe oun ko gbọdọ fọrọ naa ṣere rara, lojuẹsẹ lo ti ran Jamiu ati Ọmọga lọọ da apejọ buruku to n ṣẹlẹ nisọ ẹlẹran ru.

Ọmọga kii fẹẹ gbọrọ Adisa seti, ṣe lọrọ naa dabi igba ti baba ọja kan epo bẹntiro sina to n jo wẹrẹwẹrẹ niyẹn ba bu laulau soke, latẹyin ni wọn ti yẹ aga mọ ọ nidii, alakọri ẹ kuku fuyẹ tẹlẹ koda ko sẹni to gburo gbii nilẹ ṣe lo danu bi ẹwa wooro. Ṣe kii ṣoju ina niṣu ewura ni maa hu irun, ẹni ori yọ dile lawọn yooku fọrọ naa ṣe koda ẹlomin-in ko duro ko bata.

Aṣọti ọrọ lo kuku n jẹ ọmọ mi gbẹna, emi ti mo ti mọ iru itu tawọn ẹruuku fẹẹ wa pa nibẹ naa ni mo tun n sọ pe ‘Ki lo de, Jamiu ani ki lo de, mo ni ki lo ṣẹlẹ’ koda mo pa kuuruku mọ Ọmọga, mo ni bi ko ba sọ oun to ṣẹlẹ fun mi ṣe ni mo maa gba oju ẹ. Ọrọ ti mo sọ fun Adisa oponu ni ikiya diẹ, o ni, ‘Abẹbi ba mi bi wọn o, iṣubu mi ni Ọmọga n wa o ṣugbọn Ọlọrun ko ni fun un ṣe’ ba a ti n sọrọ yii lawọn to ti salọ tẹlẹ n yọju diẹdiẹ, wọn rii pe mo ti da si i, ṣebi ayafi ki Ọba Aṣẹda gba wa lọwọ a-ṣe-ni-ba-ni-daro. Kii ṣe pe mo fẹẹ gbeja alakọri ara ẹ bi ko ṣepe mo fẹẹ ki awọn to salọ pada wa gbọ idi ti wọn ko gbọdọ fi ṣe iru ipade bẹẹ mọ.

Awọn Jamiu ṣalaye idi ati itumọ ti wọn fi yẹyẹ Adisa alaṣeju,wọn ni ipade to n ṣe ko nitumọ, gẹgẹ bi ọkan lara ọmọ igbimọ ọja, ko lẹtọọ lati ṣepade kan lai gbaṣẹ lọwọ awọn alaṣẹ ọja. Lootọ gbogbo ọmọ igbimọ ọja ni wọn mọ pe bi gbogbo eeyan ba n kọrin oro ṣe ni Adisa yoo maa kọrin egungun ni tiẹ ṣugbọn bi kinni buruku kan to dabi arugbo ọbọ naa ba gbọn ni, o yẹ ko ti mọ pe ilodi si aṣẹ ọja maa n ṣakoba foun ṣugbọn ko nii gbọ, ọkọ Alaaja Taiba lo maa n ba lọ, abi ẹ ti gbagbe alaaja Taiba, ọrẹ iyalọja to gbe igbimọ ọja lọ si kọọtu lọjọsi to ku lasiko ajakalẹ arun korona, oun lo ṣi n lo Adisa gẹgẹ bi irinṣẹ nitoripe oun naa fẹẹ jẹ babalọja. Ọkunrin yẹn lo gbe ẹgbẹ to tako eyi tawọn alaṣẹ ọja n ṣe wa, Adisa si lo n ba a tukọ ẹgbẹ naa laarin ọja koda, ofo to ṣe wọn lọjọ naa kii ṣe kekere nitori ṣe ni Jamiu palẹmọ owo ti wọn fẹẹ pin nilẹ to si ju u si Tayelolu to rọra sapamọ sibikan tiyẹn si gbowo salọ.

Lẹyin-o-rẹyin taa kilọ fun Adisa tan lo ni ki wọn gbe owo apo ti wọn fọwọkọ silẹ ṣugbọn ko sowo kankan lọwọ awọn mejeeji, bi alakọri Adisa ti n pariwo pe wọn gbowo lawọn eeyan n sọ pe owo naa da lọwọ wọn,ṣe emi nikan ni mo ri Tayelolu ṣugbọn mo ṣebi ẹniti ko ri nnkankan, bii  mọnamọna ni wọn ṣiṣẹ ọhun koda ṣeni ẹni to gbowo naa dapọ mọ awọn ero to n sa asala fun ẹmi wọn  lawọn eeyan ba bẹrẹ sii bu u, wọn ni aṣe irọ lo fi tan awọn jokoo, owo to sọ pe o wa nilẹ naa lo tun sọ pe wọn ti gbe yẹn ṣugbọn ti ko sowo lọwọ awọn to parọ mọ, ẹnikan tiẹ sọpe ‘Ṣebi awọn mejeeji naa ni wọn ṣi wa nibi ti ko sowo lọwọ wọn yii, abi irọ ojukoroju wo wa ree’.

Bi ale iya ẹni ba ju baba ẹni lọ, baba la a pe e, Adisa ko le sọrọ mọ ṣe lo kajọ bi adiyẹ to ṣẹṣẹ da ọmọ nu bẹẹ lawọn eeyan n wẹnu si i lara koda wọn tọlẹ la, wọn ni bo ba tun pe ipade radarada kan, ṣe lawọn maa yọ ila ẹẹkẹ rẹ lẹyọkọọkan tawọn a bẹrẹ si fi na an. Ọrọ buruku pẹlu ẹrin,Oṣelu la fi han alakọri ẹ, ṣe ko mọ pe ẹni to ba maa ba eṣu jẹun, ṣibi rẹ gbọdọ gun, mo bẹru oṣelu jare, ọrọ oṣelu toto!.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp