Olori ijo Ridiimu, iyen Redeemed Christian Church of God, Pasito Enoch Adeboye, omo mejila lo wu oun lati bi tele, nitori oun feran omobibi pupo-pupo, sugbon oun ko ri awon omo mejila naa bi.
Baba Adeboye ti awon omo ijo re maa n saaba pe ni Daddy GO, bo tie je pe oun ko ri iye omo bee bi, sugbon Olorun ti fi awon ogunlogo omo emi da oun lola kaakiri ibi lagbaaye.
Adeboye soro yii nibi ipago alaadorin odun won to n lo lowo ibi ipago naa to wa ni ojuna Eko si Ibadan.
Ninu ipago naa, awon omo metadinlaadorin ni won bi; awon okunrin mokanlelogoji, awon obinrin merindinlogbon.
Akori ipago naa ni Jubili Pipe, bere lojo Aje, Monde, yoo si pari lonii ojo Sannde, ojo kerinla.
Baba naa sapejuwe ijo Ridiimu bii ibi ti Olorun ti n gbo adura awon to n woju Oluwa fun ebun omo, o ni, laipe ko ni si agan mo ninu ijo naa. Nitori mo feran omo pupo.
