Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ṣabẹwo si awọn oniroyin ti awọn janduku kọlu lanaa Sannde lasiko ti wọn lọọ ṣiṣẹ ikini kaabọ Aṣiwaju Bọla Tinubu l’Ekoo. Gbọngan yara iroyin awọn oniroyin naa to wa ni Bagauda Kaltho ni Alausa, Ikẹja ni gomina wa.

Meji ninu awọn oniroyin naa ni awọn janduku yii kọlu ni Isalẹ Eko, loju ẹsẹ ni wọn si ti gbe wọn lọ sileewosan fun itọju.

Nigba to n ki awọn oniroyin naa pẹlẹ niṣoju olori awọn oṣiṣẹ rẹ, Ọgbẹni Tayọ Ayinde ati akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Gboyega Akọṣilẹ, gomina ni awọn oniroyin ko gbọdọ jẹ ki ewu to wa lẹnu iṣẹ naa da aarẹ ọkan si wọn lara.

O ni; “Iṣẹ yin ko rọrun, ewu pupọ wa nibẹ, ṣugbọn ẹ gbọdọ ṣe giri pẹlu igboya lati ni suuru.”

Bakan naa lo sọ pe awọn alabosi kan ni wọn fẹẹ lo ohun to ṣẹlẹ naa lati tabuku ijọba, eyi lo fa a toun fi paṣẹ pe ki wọn ṣewadii iṣẹlẹ naa kiakia. O ni, gbogbo awọn to lọwọ siṣẹlẹ naa ni wọn gbọdọ wa jade ki wọn si fi wọn jofin.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp