
Ninu ọgba ẹwọn Kirikiri to wa ni Eko ni Wolii Israel Ọladele ti ọpọ eeyan mọ si Genesis ti ṣe isin rẹ akọkọ lẹyin ti ileẹjọ sọ ọ sẹwọn ọdun kan gbako fun ẹsun jibiti to lu ọmọbinrin kan to filuu oyinbo ṣebugbe.
Wolii Israel Ọladele Ogundipe jẹ oluṣọ ileejọsin ijọ Celestial Church of Christ Global Genesis. Ọsẹ to kọja yii ni ileẹjọ ju ọmọkunrin gbajumọ pasitọ naa si ẹwọn ọdun meji, ṣugbọn awọn amofin ni, ọdun kan pere lọmọkunrin naa maa lọ lọgba ẹwọn.
Ohun ti Aṣejere gbọ ni pe awọn ọmọọsẹ ojiṣẹ Ọlọrun naa ni wọn ṣe isin fawọn ọmọ ijọ lonii ọjọ isinmi Sannde ni ṣọọṣi naa, ṣugbọn inu ṣọọṣi to wa lọgba ẹwọn ni Genesis ti ṣe isin tirẹ lọjọ isinmi, a gbọ pe o ṣe e pẹlu awọn ẹlẹwọn ni.
Adajọ Ọlabisi Akinlade, lo ju ojiṣẹ Ọlọrun naa ṣẹwọn lẹyin to fidi ẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an. Ẹsun meje ni wọn fi kan an, ṣugbọn o jẹbi meji ninu awọn ẹsun naa.
Arabinrin Ọlaide William Oni lo ran Genesis lọ sẹwọn, oun lo gba lowo tiye rẹ to miliọnu mọkanla naira.
Ọdun 2007 ni ẹjọ ọhun ti wa nileẹjọ, ṣugbọn gbogbo igba ti wọn ba lọ sileẹjọ ni Wolii Ọladele maa n sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
