Oloye Aluko

Ifa lo ni ile aye, Olodumare lo ni ọrun. Ọrunmila lo ni ilẹ bẹẹ lo fa itọsọna le awọn kan lọwọ. Lara awọn koṣeemani la ti ri Oloye Kamaldeen Adekunle Aluko ti a bi sinu ẹbi Aluko ni ilu Kajọla Ibẹju Lẹkki nipinlẹ Eko. Gẹgẹ bi ohun ti wọn ba akọroyin wa sọ, Oloye ṣalaye pe inu idile oniṣẹṣe pọnbele ni wọn bi wọn si ni nnkan bii ọdun diẹ sẹyin. ‘Mo jẹ Saba to n nawọ si igunnuko bẹẹ lawọn aworo ṣaṣa ri ipa ribiribi ti mo ko ati iṣẹ takuntakun ti mo n ṣe ninu ọrọ ilu ati iṣẹṣe ni wọn ṣe fi mi jẹ alaga ẹgbẹ AATREN ni ilu Kajọla ati agbegbe Ibẹju Lekki lapapọ’.

Ka sọrọ eeyan ka baa bẹẹ niyi ọmọluabi, Oloye Kamaldeen daa nile bẹẹ ni wọn daa nibi gbogbo, eyi lo tun mu ki wọn fi wọn jẹ awọn oye ti ko ṣee foju parẹ bii, alaga Olomitutu ti ilu Ibẹju Lekki, Ọtunba itage eti ọsa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Odu ni Oloye Kamaldeen wọn kii ṣe aimọ fun oloko, ọdun ifa ti wọn maa n ṣe lọdọọdun kọja afẹnuroyin. Ọsẹ kan gbako ni wọn maa fi n ṣee, tọdun yii yoo larinrin yatọ, asiko wa lati beere ohun to n wu Ẹlẹda ẹni lọwọ ifa. Ọjọ kejila oṣu kejila ọdun yii ni aṣekagba ti yoo rinlẹ.

Wọn ni oriṣa ti eeyan ba n ṣe to fi pamọ fun ọmọ rẹ, o daju pe iru oriṣa bẹẹ ko ni pẹ parun. Nibi ti Oloye Kamaldeen fẹran iṣẹṣe de, ṣe lo fi ọju awọn idile rẹ, tọmọ taya mọ iṣẹṣe atawọn irunmọle laifi ọrọ naa falẹ rara.

Ki a yọ tẹgan kuro koda ka tun fi tẹgan kun un, Ọga ni Oloye Kamaldeen nibi ka ko eeyan mọra, tonile talejo ni wọn mọ pe awọn ti de ebute ifọkanbalẹ bi wọn ba ti de agbala wọn. Ipo pataki ni wọn fi awọn ọdọ si ‘Awọn ọdọ jẹ awọn ọjọ ọla wa tori naa o ṣe pataki ka maa tọ wọn sọna, ki a si foju wọn mọ awọn oriṣa wa. Nnkan to lewu fun ọjọ ọla orilẹ-ede kan ni bi awọn ọdọ ko ba mọ oju iṣẹṣe awọn baba nla wọn. Nitori naa, mo gba awọn ọdọ ni imọran lati foju si iṣẹṣe toripe iṣẹṣe lagba ohun gbogbo.

Lakotan, mo lo anfaani yii lati sọ fun gbogbo eeyan pe ki wọn ma ṣe fọwọ yẹpẹrẹ mu iṣẹṣe toripe ẹsin ajogunba ni bẹẹ wọn ni ọmọ kii ba ipele iya rẹ nile ko ṣi aṣọ da. Ọlaju ko gbọdọ gba ẹsin abalaye lọwọ wa, ohun kan to daju ni pe, ojuṣe wa ni gẹgẹ bi ojulowo ọmọ Yoruba lati maa bo oro ile ẹni toripe oro ile ẹni ni i gbeni.

Ko si ẹni to kọja adanwo ṣugbọn mo wure fun gbogbo eniyan ki wọn ma ṣe ri adanwo ti yoo ju ẹmi wọn lọ, bi o ba nilo lati ṣayẹwo tabi o n fẹ ki a yo e sọna, kan si wa ni 10 Oketapa, Tapa street, Kajola Town Ibẹju Lekki Lagos, tabi ki ẹ pe ẹrọ ibanisọrọ wọnyi 08088878061. Iṣẹṣe lagba lotitọ.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp