
Ọrọ owo ajẹmọnu ifẹyinti Abilekọ Oyeṣọla Ogunlẹyẹ ti ko fi bẹẹ ye ọpọ eeyan ree o. Ohun ti Aṣejere gbọ ni pe obinrin yii jẹ oṣiṣẹ banki naa tẹlẹ, ọdun 1998 ni wọn gba a siṣẹ, ṣugbọn ileeṣẹ ti wọn gba a si nigba naa ni wọn n pe ni Magnum Trust Bank Ltd, wọn si fun un niwe iṣẹ gẹgẹ bii oṣiṣẹ wọn.
Ṣugbọn nigba ti banki agba ilẹ wa, iyẹn CBN gbe ofin jade lati fofin de awọn banki kan, ni oṣu kinni, ọdun 2006, ileefowopamọ NAL Bank darapọ mọ awọn banki mẹrin kan, awọn naa ni; Magnum Trust Bank, NBM, Trust Bank of Africa ati Indo-Nigeria Merchant Bank (INMB).
Awọn banki yii ni wọn parapọ waa di Sterling Bank. Eyi lo fa a ti wọn fi gbe faili obinrin opo ọlọmọ-mẹrin yii wa si ọdọ Sterling Bank PLC, ṣugbọn wọn ko sọ eyikeyi ninu awọn owo ti wọn jẹ ẹ, ohun ti wọn kan sọ fun un ni pe wọn ti gbe faili rẹ lọ si ọdọ ileefowopamọ Sterling Bank PLC.
Nigba to di ọdun 2011, wọn le obinrin yii kuro lẹnu iṣẹ, bẹẹ si ni banki ọhun kọ lati san gbogbo awọn owo ajẹmọnu obinrin naa. Lara awọn owo ti wọn kọ lati san ni awọn owo ti wọn n yọ ninu owo oṣu rẹ, loṣooṣu lati ọdun 1998 di inu oṣu kejila ọdun 2005. Bẹẹ ni ko tun si akọsilẹ kan to fihan pe wọn n sanwo rẹ lati 2006 di ọdun 2011.
Nigba ti obinrin yii ri i pe ẹbẹ ko le e yanju ọrọ naa, lo ba gba ileẹjọ lọ lọdun 2014, ṣugbọn ileefowopamọ naa kọ lati bọwọ fun idajọ ileẹjọ.
Titi di bi a ṣe n kọ iroyin yii, ileefowopamọ naa ko ti i ṣe ohun kan lati san owo obinrin naa, ṣe ni wọn n fẹsẹ falẹ lati mu idajọ ileẹjọ lori ọrọ naa ṣe.
