Aare tuntun ti won sese fun fun ajo olokoowo to so ile Asia ati ile Afika, eyi ti a mo si Asian-African Chamber of Commerce and Industry, Ogbeni Arinle Adekunle Ahmed, ti so o di mimo koko ohun ti isakoso oun fee gunle ni bi airisise awon odo yoo se dinku nile wa Naijiria, ati bi won yoo se lanfaani ati kekoo lodo awon olokoowo kaakiri agbaye.

Anrinle soro yii lojo Tosde leyin to pada de lati ipade awon olokoowo naa to loo se ni ileetura The Grand Hotel, New Delhi, nile India lohun un. Ibe ni won ti yan an sipo Aare egbe ajo naa.
Ajo egbe awon olokoowo ile Afrika ati Asia yii ni omo egbe kaakiri awon orile-ede ile Asia, Afrika, Amerika, Australia, Europe pelu awon omo egbe ti won le logofa kaakiri agbaye.

Bakan naa lo tun seleri pe pelu iranlowo Olorun, oun setan ati lo ipo naa gege bii Aare ati safihan lati lo saa toun ni lati je ki awon odo ile wa mo anfaani to wa fun won lodo awon olokoowo lawon orile-ede agbaye, nipa isowo, idanilekoo, ati lawon eka oja to wa nile naa.
O tun so pe lai fakoko sofo rara, ise naa ti bere ni pereu, bee loun maa so won po pelu awon olokoowo ti won maa se anfaani fun won.

Nibi ipade ohun to waye nile India, Anrinle so pe opo awon asoju ijoba, leka isejoba ati oro aje ni won peju sibi ipade naa ti won si setan ati fowosowopo pelu awon ti won wa leka oro aje. O ni idi tawon fi gbe ajo naa kale ni lati ohun ti n fa awon orile-ede kan seyin.
Awon anfaani to wa leka oro aje ni orile-ede kookan ni won gbe yewo, ti won si soro le lori lati mo anfaani to wa nibe fun awon odo ati awon olokoowo ti won fee mu ki oro aje won fe si i nibi ti won wa.

Awon ti won wa nibi ipade naa ni Ogbeni Gabriel P. Sinimbo – asoju ile Namibia; Deliwe Mumbi – igbakeji asoju ile Zambia; Nomusa Mugwambi – olugbaninimoran lori isowo nile Zimbabwe; Vitaly Mirutko – olugbaninimoran lati ile Belarus; Vladimir Poghosyan – asoju ile Armenia; James Nhlane – akowe oselu ile Malawi; ati Jared Bironga Mayieka – asoju ile Kemya lori oro aje.

Awon yooku ti won tun wa nibe ni Alagba Mahesh Sachdev – asoju ile India tele; Suresh Goel; Mumunur Rahman; Coubageat Malik, Togo ati Ogbemi Anrinle Ahmed Adekunle.
Anrinle ni igbakeji Aare ajo naa tele nile Naijiria, bee ni won si tun je omo igbimo to n gbaninimoran. Ohun taa gbo ni pe laipe ki odun too pari ni won maa sefilole igbimo tuntun yii nileetura Eko Hotel & Suites.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp