Iroyin to n te wa lowo fi han pe awon agbaboolu obinrin ile wa, iyen awon ti ojo ori won ko ju odun metadinlogun lo, ti se ipo keta ninu idije ere boolui alafesgba to n lo lagbaye.

Orile-ede Germany ni awon odobinrin naa gbon ewuro soju won lati se ipo keta ninu idije agbaye naa.

Penariti lawon omo naa fi bori ninu ifesewonse naa leyin ti won ta omoi ayo meta-meta leyin ti won pari ifesewonse naa ni aadorun iseju.

Awon omobinrin wa lo koko ju boolu meta sawon, ko too di pe awon jamani naa fi oba le e ti ayo naa si wo penariti.

Ninu penariti naa, Naijiria gba meta sawon, nigba ti Jamani gba meji si awon, lawon omo wa ba jawe olubori.

By Asejere

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Follow by Email
WhatsApp